Ìlú yóò le, ọmọ le kú, àìsàn yóò pọ̀ bí eégún kò bá jáde nílùú Ibadan - Olóòlù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ni ẹ jẹ ka ṣe bi wọn tii ṣe, ko lee ri bo ti yẹ ko ri, ko maa ba lẹyin bii oku iya jọjọ.
Eyi ni esi ti ọkan lara awọn eegun ilẹ Ibadan, tii tun ṣe Oloolu baba eegun, Ifasuyi Omotoso Kazeem fi fesi si aṣẹ ti Olubadan pa.
Bẹẹ ba gbagbe, Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun lo ti pasẹ pe ki awọn egungun mase jade mọ jakejado ilẹ naa.
Eyi ko si sẹyin iwa jagidi jagan ti wọn n hu, eyi to n ko ijamba ba araalu ati dukia wọn.
Bẹẹ ba gbagbe, a ti kọkọ mu iroyin yii wa fun yin lọdun 2020 pe, Olubadan tilẹ Ibadan to ti gbesẹ bayii, Ọba Saliu Akanmu Adetunji paṣẹ pe egungun kankan ko gbọdọ jade fun ọdun eegun, nitori arun Coronavirus.
Oniruuru arun ni yoo bẹ silẹ, bi eegun ko ba jade - Oloolu
Amọ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesẹ naa lọdun 2020, Oloolu ni oun ko gbọ ri rara pe ni ọdun kan, eegun ko ni fi aṣọ wọlẹ nilu Ibadan.
Oloolu ni "awọn nnkan to maa n sẹlẹ lẹyin rẹ maa n lagbara, Ọlọrun ma jẹ ka ri ogun igbona, Coronavirus si ree, igbona lo bii,aṣọ eegun si lo maa n ko arun kuro nilu.
Agba eegun naa ni idakureku ojo to n waye laarin ìlú, isoro nla ni, orisirisi arun ni yoo si maa bẹ silẹ, to fi mọ arun ti a ko gbọ ri.
"Aṣẹ ti ijọba pa fun Olubadan lo sọ sita, oun ti ko si ye ijọba ni pe egungun la fi tẹ Ibadan do, bi eegun ko ba si jade, isoro yoo sẹlẹ, Ọlọrun ma jẹ ki aburu ṣe wa."
"Mo ti rí ibi tí eléégún kan ti pàdánù ọmọ méjì nígbà tí ìjọba ní kó má jáde ní ọdún kan"
Oloolu tẹsiwaju pe "Ọrọ bii wahala ni yoo maa sẹlẹ n'Ibadan, ọrọ bii ogun, bii ọtẹ, awọn etutu kan wa ta maa n ṣe fun ọba, bawo wa ni yoo ṣe wa di sise lọdun yii, ti wọn yoo ni ka ma ṣe etutu ọhun amọ ka jokoo sile."
Oloolu tẹ siwaju pe awọn egungun kan wa to jẹ pe ti wọn ko ba jade, nnkan yoo ṣe awọn to n gbe eegun naa, to si fi eegun kan ti wọn ni ko ma jade ni ọdun kan ṣe apẹẹrẹ, o ni ọmọ ẹni to n gbe eegun naa meji lo ku.
"Eyi to ṣẹlẹ yii, bii igba ta kan da wahala sira wa lọrun ni. Ki Ọlọrun ma jẹ ka ri wahala."
Oloolu, ẹni to ni oun ko tii le sọ boya ijọba yoo fun oun lasẹ lati jade ṣe ọdun ni ọdun yii abi bẹẹ kọ wa fi ọwọ gbaya pe bi ijọba ko ba fun oun lasẹ lati jade, oun yoo ṣe iwọnba ohun ti oun ba le ṣe niha toun, amọ ohun ti yoo ti ẹyin rẹ yọ, ni oun ko le sọ,tori mẹwa yoo sẹlẹ.
Olubadan wọ́gilé ọdún eégún, ó ní kí àwọn Alaagbaa péjú sí ìpàdé pàjáwìrì
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Olubadan Ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun ti paṣẹ ki wọn so ọdun egungun to n lọ lọwọ rọ ni kiakia titi di ọjọ mii.
Aṣẹ oriade yi ko ṣẹyin iroyin to gbode pe awọn oni jagidijagan kan to ṣa sabẹ ọdun eegun yi n ṣe ikọlu, dana sun ile ti wọn si n fọ ṣọọbu awọn araalu.
Lọjọ Aiku yi ni Olubadan fi ikede yi sita ninu atẹjade kan lati ọwọ agbẹnusọ aafin Oladele Ogunsola.
Ọba naa tun kesi awọn olori ikọ eegun kọọkan taa mọ si Alaagba ni ilẹ Ibadan pe ki wọn wa sibi ipade pajawiri kan laafin lọsan ọjọ Aje.
Kabiyesi fi itara han bi orisirisi iroyin ikọlu ati iwa jagidijagan ṣe gbode lasiko ọdun egungun yi.
Bẹẹ lo ni inu oun ko dun si fọnran fidio to gbode ti Kabiyesi si ṣapejuwe iṣẹlẹ yi gẹgẹ bi itabuku aafin nitori oun ti kilọ pe ki wọn ma sọ eegun di ọna ati da wahala silẹ.
Mo ti ṣaju lọgun lori jagidijagan lasiko ọdun eegun

Oríṣun àwòrán, Facebook/kehinde.saheed.372
Kabiyesi Lekan Balogun ninu atẹjade naa ṣalaye pe Ọjọru to kọja loun ti ṣaaju lọgun lori irufẹ ikọlu to waye lagbegbe Alafara Olubadn laipẹ yi.
Ọba ilẹ Ibadan sọ pe ''Mo kilọ fun wọn lori nkan to n ṣẹlẹ yi ṣaaju ki wọn to bẹrẹ ọdun eegun yi.
"Wọn sọ fun mi pe ko ni si laburu, amọ iroyin to n tẹ mi leti bayii fihan pe ọrọ tawọn olori eegun sọ ti yatọ si nkan to n ṣẹlẹ''
O tẹsiwaju pe ''Ko si olori ti yoo kawọ rọ tawọn araalu to n dari ba n kerora nitori iwa buruku awọn kan lawujọ ko fẹ tẹle ofin.
"Idi ree to ṣe di dandan pe ki wọn so ọdun yi rọ fun igba kan naa. Igba ti a o gbẹsẹ kuro lori aṣẹ yi di nkan taa jiroro le ti abajade ipade ọjọ Aje yoo si ṣe atọna rẹ''
Kabiyesi wa kesi awọn agbofinro lati ri pe ẹni ti o ba lọwọ ninu ikọlu yi ko lọ lae jiya.
Kabiyesi sọ pe oju ọdaran gidi ni ki wọn fi wo ẹnikẹni ti aje ọrọ naa ba ṣi le lori.
Kii ṣe iroyin mọ wi pe oniruru rogbodiyan lo maa n waye lasiko ọdun egungun ni ilu Ibadan atawọn ilu miran kaakiri ipinlẹ Ọyọ.
Wahala ati rogbodiyan lasiko ọdun egungun wọpọ kaakiri ipinlẹ Ọyọ.
Ko si igba ti ijọba kii ṣe ifikunlukun pẹlu awọn olori eegun ṣaaju ki ọdun yi to waye.
Koda ọrọ naa mumu lọkan ijọba debi pe wọn pe ipade lati jiroro lori mimu atunṣe ba aṣa yi.
















