Ọlọ́pàá ń ṣèwádìí bàbá ọmọ fún ẹ̀sùn pé ó ta ọmọ rẹ̀ mẹ́ta ní N1.5m

Ọwọ Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Rivers ti tẹ arakunrin kan àtàwọn mẹfa mii fun ẹ̀sùn pe wọn ta ọmọ rẹ mẹta ni iye owo mílíọ̀nù kan àbọ̀ naira.
Agbenusọ Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ naa, SP Grace Iringe-Koko sọ fun awọn oniroyin pe ọwọ tẹ ọkùnrin náà ni Ọjọ Abamẹta ọjọ Kẹjọ Oṣù Keje ọdun 2023 ni nnkan bii ago marun irọlẹ.
O ṣàlàyé o ni wọn fẹ̀sùn kan pe arakunrin naa ta awọn ọmọ rẹ ti wọn jẹ ọdun marun, ọdun meji ati ọmọ ọjọ kan ni iye owo N700,000, N500,000 ati N350,000 ni igba ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nitori bi ọrọ aje ṣe le koko nilu gẹgẹ bo ṣe sọ.
"Ó ni oun ko le tọju awọn ọmọ naa ati pe iyawo rẹ jẹ odi ti ko si le sọ̀rọ̀."
Ẹgbẹ́ fijilante adugbo naa ni ijọba ìbílẹ̀ Ikwerre, Ìpínlẹ̀ Rivers lo mu ọkùnrin ọhun ti wọn si gbe e lọ fun awọn Ọlọpaa to wa ni Elele àwọn si ni wọn padà fi ẹjọ́ rẹ ṣọwọ si ikọ Komiọna.
Nígbà to n fi oju awọn afurasi méje tí wọn mú hàn, o ni bi awọn ṣe gba wọn mu ko sẹhin àṣírí to tu latenu awọn afurasi méjì kan tí àwọn ti mu ṣáájú.
"Iwadii lo gbe wa wọ ijọba ìbílẹ̀ Emohua àti ìlú Mbaitoli ati Ogbaku nibi ti ọwọ tí tẹ awọn afurasi naa''
Ó fi kun un pe awọn ti ọwọ tẹ yìí ti jẹwọ pé lóòótọ́ ni awọn ti gba ọkan ninu awọn ọmọ náà ti wọn si pada gbe ọmọ naa fun Kanselọ tẹ́lẹ̀ rí kan ni ijọba ìbílẹ̀ Rukpokwu ni Obio/Akpor amọ a ko le dárúkọ rẹ.
SP Iringe-Koko sọ pe awọn ti fi panpẹ ọba mu kanselọ naa to si sọ fawọn pe oun bá arabinrin kan sọ̀rọ̀ ni ilu Aluu nibi to ti ta ọmọ oojọ fun oun niwaju baba ọmọ náà.
"Bákan náà, a ti mu obinrin ọhun o si gba pe oun ra ọmọ ọhun ni N700,000 ti wọn si san N350,000 fun baba ọmọ naa ati N350,000 fún kanselọ tẹ́lẹ̀ rí ọhun àtàwọn alàbaṣiṣẹ́ rẹ."
SP Iringe-Koko jẹ ko di mimọ pe awọn ti ri ọmọ ọdun meji naa ati ọmọ ikoko ti obinrin to wa ni Aluu ra bẹẹ si lo ni iwadii ti n lọ lọwọ lati ri ọmọ ọdun marun to ku naa gba.
"O maa n sọ fun mi pe gbogbo ọmọ ti ọmọ mi n bi lo n kú'' - Iya ìyàwó

Ẹwẹ, iya ìyàwó arakkunrin to ta awọn ọmọ rẹ ni ni ṣáájú ki Ọlọpaa to gbé e, o máa n parọ pe awọn ọmọ ọmọ oun paapaa eyi to jẹ abigbẹyin ti ku nigba ti wọn bi i.
Ó sọ fawọn oniroyin pe afurasi naa lo anfani pe odi ni ọmọ oun to si fi ṣe gbogbo iṣẹ ibi naa.
"Ojojumọ lo n sọ fun mi pe ọmọ ti kú, àkọ́kọ́ ó kú, eleyii náà o tun kú, kí ló ń ṣẹlẹ̀ gangan? Ni mo ba ni ko wa fi ibi to sin òkú ọmọ àkọ́kọ́ si, ko le fi han mi, mo ba so o mu pe awọn ọmọ mi dà?
Ṣe toripe ọmọ mi ko le sọ̀rọ̀ lo ṣe n ṣe e báyìí?!
Bi mo ṣe figbe ta lo mu ki awọn ara Omerelu jáde sita pe emi ni iya ọmọ naa bi mo ṣe lọ pe awọn figilante Omerelu nìyẹn ti wọn wa gbe e lọ si agọ Ọlọpaa".
Agbẹnusọ Ọlọpaa ni awọn gbogbo awọn afurasi ni awọn yóò gbe lọ sí ilé ẹjọ́ lẹ́yìn iwadii ti wọn n ṣe.

















