Ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé mú ẹ̀mí ogun èèyàn lọ ní South Korea, ẹgbẹgbẹ̀rún di aláìrílégbé

South Korea floods

Oríṣun àwòrán, Reuters

O kere tan, ogun eeyan ti lo jade laye, nigba ti ẹgbẹgbẹrun di alairilegbe latari iṣẹlẹ omiyale to waye ni South Korea.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ti ojo rọ fun ọjọ mẹta gbako, eyii to ba ọpọlọpọ dukia jẹ kaakiri orilẹ-ede naa.

Iroyin ni ojo naa pọ to bẹẹ to bo adagun omi kan mọlẹ ni iha Ariwa Chungcheong.

Olootu ijọba orilẹ-ede naa, Han Duck-soon, ti ke si ileeṣẹ ọmọ ogun fun iranwọ lati doola awọn eeyan to ṣi ha sinu iṣẹlẹ ọhun.

Ijọba ilẹ naa sọ pe eeyan mẹwaa lawọn ṣi n wa bayii, nigba ti ọpọ ninu wọn farapa.

Ko din ni ẹgbẹrun mẹfa ati irinwo eeyan ti wọn ko kuro lẹyin ti adagun omi ‘Goesan Dam’ bẹrẹ si n kun akunfaya lọjọ Abamẹta.

A gbọ pe awọn ilu kekeke to wa lẹba adagun omi ‘Goesan Dam’ naa ni omi ti bo mọlẹ bayii, nigba ti awọn eeyan kan ṣi wa lawọn inu ile to wa nibẹ.

Ileeṣẹ to n bojuto ọkọ oju irin, Korail, ti fofin de lilọ bibọ ọkọ oju irin lorilẹ-ede naa bayii, to fi mọ awọn ọkọ oju irin ayara bi aṣa.

Ikede yii waye lẹyin ti ọkọ oju irin kan danu ni iha Ariwa Chungcheong lasiko ti agbara ko okuta ati yẹpẹ soju ọna rẹ.

Amojuẹrọ kan farapa ninu ijamba naa amọ ko si ero ọkọ kankan ninu rẹ lasiko iṣẹlẹ naa.