Ṣé lóòtọ́ ni Peter Obi ti gba kámú, tó sí fẹ́ díje dupò ààrẹ ní 2027?

Oríṣun àwòrán, Others
Oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour party, Peter Obi ti ni ko si otitọ ninu iroyin to n ja ranyin pe o tun di ọdun 2027 ki oun to dije du ipo aarẹ ni Naijiria.
Ninu atẹjade ti Peter Obi fi lede loju opo Twitter rẹ lo ti ni ko si ohun to jọ iroyin bẹẹ lati ọdọ oun.
Obi ni itiju lo jẹ pẹlu bi awọn eniyan ṣe n gbe iroyin ẹlẹjẹ, to si ni oun ko tilẹ ba awọn oniroyin kankan sọrọ bi iroyin ẹlẹjẹ naa ṣe sọ.
Obi to jẹ gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra yọ ara rẹ kuro ninu iru iroyin ẹlẹjẹ naa.
O ni ahesọ ni iroyin naa, ti ko si otitọ ninu rẹ.
Bakan naa ni Obi ni ko si otitọ ninu iroyin pe aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu fi ipo lọ oun ni ijọba rẹ.
‘’O ti wa si akiyesi mi pe awọn eniyan n gbe iroyin ẹlẹjẹ nipa mi , paapaa awọn ifọrọwerọ ti ko tilẹ waye rara.''
''Iru iroyin ẹlẹjẹ yii ni iroyin pe mọ n gbaradi lati dije du ipo aarẹ ni ọdun 2027, ti wọn si ni lori ẹrọ amohunmaworan Arise TV ni mo ti sọ.’’
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
''O ṣeni laanu pe ko tilẹ si ohun to jọ ifọrọwerọ yii, ti ko si si ohun to jọ bẹẹ.''
Bakan naa ni wọn tun ni wọn tun ni wọn fimi si ipo ni ijọba aarẹ Tinubu, irọ ni o.’’
Oludije sipo aarẹ naa ni iwa awọn ọbayejẹ yii ko ni da oun duro lati maa ṣọrọ nipa ilọsiwaju orilẹede Naijiria.
Laipẹ yii ni iroyin gbe pe awọn ẹgbẹ osẹlu APC n gbaradi fun atundi idibo sipo aarẹ, nitori awọn gbagbọ pe ileẹjọ yoo wọgile idibo sipo aarẹ to waye ni Naijiria.














