Wo orúkọ àwọn olùrànlọ́wọ́ 20 tí Tinubu yan láti bá a ṣiṣẹ́ pọ̀

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti buwọ́lu ìyànsípò ogún ènìyàn mìíràn tí yóò máa ba ṣiṣẹ́ nínú ìjọba rẹ̀.
Àwọn olùrànlọ́wọ́ pàtàkì àti àwọn ayàwòrán wà lára àwọn ìyànsípò tuntun náà.
Lára àwọn tí Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lu ìyànsípò ni Tunde Rahman tó jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ akọ̀ròyìn tí Tinubu yàn sípò olùrànlọ́wọ́ lórí ètò ìròyìn.
Bákan náà ló tún yan Abdulaziz Abdulaziz àti Ibrahim Masari.
Ìròyìn ní Ààrẹ ti fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ìwé láti wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.
Ìyànsípò yìí ni ìkẹta gbòógì irú rẹ̀ tí Ààrẹ Tinubu ń ṣe lẹ́yìn tí wọ́n búra wọlé fún gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà lọ́jọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún.
Ní ọjọ́ Kejì oṣù Kẹfà ló yan akọ̀wé ìjọba, olórí òṣìṣẹ́ ilé ìjọba àti igbákejì rẹ̀.
Lẹ́yìn náà ló yan àwọn olùbádámọ̀ràn mẹ́jọ àtàwọn olórí Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà
Àwọn mìíràn tí Tinubu tún buwọ́lu ìyànsípò àti ipò wọn ni:
Adekunle Tinubu
Damilotun Aderemi
Toyin Subair
O'tega Ogra
Demola Oshodi
Tope Ajayi
Yetunde Sekoni
Motunrayo Jinadu
Segun Dada
Paul Adekanye
Friday Soton
Shitta-Bey Akande
Nosa Asemota
Kamal Yusuf
Wale Fadairo
Sunday Moses
Taiwo Okanlawon
Àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn tí Tinubu yàn sípò
Tunde Rahman

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Ogbóǹtarìgì akọ̀ròyìn ni Tunde Rahman, tó jẹ́ Agbẹnusọ Tinubu ṣáájú ètò ìdìbò tó gbé Tinubu wọlé gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.
Ọmọ bíbí ìlú Iwo ní ìpínlẹ̀ Osun ni Tunde Rahman.
Ó ti ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn bí i Daily Times, Punch, This Day àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Láìpẹ́ yìí ni ó gba oyè onípò kejì ni ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Leicester ní United Kingdom.
Abdulaziz Abdulaziz

Oríṣun àwòrán, Twitter
Akọ̀ròyìn náà ní Abdulaziz tí òun náà sì ti ṣiṣẹ́ káàkiri àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn bíi Leadership, Blueprint, Premium Times àti Daily Trust.
Abdulaziz, tó jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Kano ti fìgbà kan jẹ́ Agbẹnusọ alága tẹ́lẹ̀ rí fún àjọ EFCC, Nuhu Ribadu.
Temitope Ajayi
Ajayi jẹ́ òǹkọ̀wé tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ikọ̀ ìpolongo fún Tinubu ṣaájú eto ìdìbò Ààrẹ.
Ìròyìn ní ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìwé ìròyìn Western Post.
Ilé ẹ̀kọ́ Obafemi Awolowo ló ti parí kó tó tẹ̀síwájú láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ dókoòwò ìpínlẹ̀ Eko.
Ibrahim Masari

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Masari ni wọ́n kọ́kọ́ fi delé gẹ́gẹ́ bí igbákejì Ààrẹ Nàìjíríà kí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC tó fenukò láti yan Kashim Shettima.















