Ẹ wó bí ìgbẹ́jọ́ táko èsì ìdìbò tó gbé ààrẹ Tinubu wọlé ṣe lọ lónìí ní iléẹjọ́...

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti pari igbẹjọ rẹ ni ileẹjọ lori lori ẹsun ti oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oselu Labour, Peter Obi pe tako esi idibo to gbe aarẹ naa wọle.
Sẹnetọ Opeyemi Bamidele to jẹ olu-osọjumikoro wọn ti awọn oloyinbo n pe ni star witness ni awọn agbẹjọrọ fun aarẹ Tinubu pe lati wa fi idi igbẹjọ wọn mulẹ.
Awọn agbẹjọro naa ni ẹni kan gboogi ti wọn nilo niyẹn fun ọrọ rẹ, ti awọn kosi ni pe ẹlomiran.
Oṣojumikoro APC naa to jẹ agbẹjọro ni orilẹede Amẹrika to si jẹ adari ọmọ ile aṣofin to pọju lọ ni ile aṣofin agba sọ fun ileẹjọ pe Tinubu ko ni ẹjọ kankan lati jẹ ni orilẹede Amẹrika.
Ṣẹnetọ Bamidele fikun un pe ni ipinlẹ Kano, wọn ji ibo Tinubu to jẹ 10, 924 gbe lọ, ti wọn ko si kaa fun ni ipinlẹ Kano.
Saaju ni igbẹjọ to n gbọ ẹjọ esi idibo naa fidi rẹ mulẹ pe awọn ti gba iwe ẹri Tinubu, ti fasiti Chicago State University fi ranṣẹ gẹgẹ bi akẹkọọ wọn ni igbakan ri.
Awọn agbẹjọrọ naa fi iwe ẹri naa lede lati fihan pe Tinubu lọ si ileẹkọ ni ilẹ Amẹrika, to si kẹkọ jade.
Lara awọn ohun ti wọn fi lede ni ile ẹjọ ni iwe ẹri ti wọn fi fun ni anfaani lati wa kẹkọ ni ileẹkọ wọn.
Bakan naa ni wọn fi iwe irinna Tinubu lọ si orilẹede Amẹrika lati ọdun 2011 si 2021 ati awọn nkan miran.
Ẹwẹ, awọn agbẹjọrọ aarẹ naa tun safihan iwe awọn ọmọ ẹgbẹ Labour Party ni ipinlẹ Anambra, ti o si ṣafihan pe Peter Obi kii se ọmọ ẹgbẹ Labour ni ipinlẹ rẹ.
Wọn ni eyi fihan pe ko ni ẹtọ lati dije du ipo aarẹ ni idibo gbogboogbo to waye ni ọdun 2023.

















