Ṣé lóòótọ́ ni Adeleke kó mọ̀lẹ́bí rẹ̀ méjì sínú àwọn tó fẹ́ yàn ní kọmíṣọ́nà?

Ademola Adeleke àti Folasade Adeleke

Oríṣun àwòrán, COLLAGE

    • Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
    • Role, Broadcast Journalist, BBC Yoruba

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Keje oṣù Keje ọdún 2023 ni ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun ka orúkọ àwọn ènìyàn mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí gómìnà Ademola Adeleke fẹ́ yàn sípò Kọmíṣọ́nà àti olùbádámọ̀ràn ni ìpínlẹ̀ sétí àwọn ọmọ ilé.

Ọjọ́ Ajé ni Agbẹnusọ gómìnà Adeleke, Mallam Olawale Rasheed nígbà tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ ní gómìnà Adeleke ti parí gbogbo ìgbésẹ̀ láti yan kọmíṣọ́nà lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn ti ń bèèrè wí pé kí ló ń dá gómìnà náà dúró láti yan àwọn tí yóò ba ṣiṣẹ́ lẹ́yìn oṣù méje nípò.

Níbi ìjókòó ilé tó wáyé lọ́jọ́ Ẹtì ni Abẹnugan ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ náà ti ka orúkọ àwọn ènìyàn náà sí il;e tó sì gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti ṣe ìwádìí àwọn ènìyàn náà lábẹ́lé kí ilé aṣòfin tó ṣe àyẹ̀wò gbangba fún wọn.

Lẹ́yìn tí ilé aṣòfin ka orúkọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni ìròyìn gba ìgboro pé gómìnà Ademola Adeleke fi orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ méjì sínú àwọn tó fẹ̀ yàn sípò.

Èyí ló mú BBC Yorùbá kàn sí agbẹnusọ Adeleke láti mọ bí Folasade Adeleke àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Moroof Ademola Adeleke tí orúkọ wọn wà lára orúkọ tí gómìnà fi ránṣẹ́ sílé aṣòfin ṣe jẹ́ sí gómìnà.

Àna ni Folasade Adeleke kii ṣe ọmọ gómìnà

Agbẹnusọ gómìnà Adeleke, Mallam Olawale Rasheed sọ fun BBC Yorùbá pé àna ni Abílékọ Adenike Folasade Adeleke tí orúkọ rẹ̀ wà lára àwọn orúkọ náà jẹ́ sí gómìnà Adeleke.

Ó ṣàlàyé pé ìyàwó olóògbé Isiaka Adeleke, gómìnà àkọ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ Osun, ni Folasade Adeleke jẹ́ àti pé kìí ṣe wí pé nítorí pé ó jẹ́ Adeleke ni wọ́n fẹ́ fi yàn-án sípò náà.

Rasheed ní ọmọ bíbí ìlú Osogbo ni Folasade Adeleke àti pé ìjọba ìbílẹ̀ Osogbo ló ń bá jáde kìí ṣe ìlú Ede tó jẹ́ ìlú ọkọ rẹ̀.

“Folasade Adeleke kìí ṣe ọmọ gómìnà Adeleke, ìyàwó gómìnà tẹ́lẹ̀ Isiaka Adeleke ni, bí àna ló jẹ́ sí gómìnà èèyàn pàtàkì ni bàbá rẹ̀ ní ìlú Osogbo, kìí ṣe ọmọ Ede.”

Bákan náà ló tún ṣàlàyé pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Moroof Ademola Adeleke tí orúkọ tirẹ̀ náà wà nínú orúkọ náà kò tan mọ́ gómìnà Adeleke rárá.

Ó ní ọmọ bíbí ìlú Osogbo ni Ọ̀jọ̀gbọ́n náà àti pé kìí ṣe ẹbí gómìnà Ademola Adeleke rárá.

“Orúkọ tó gbajúmọ̀ ni Adeleke nílẹ̀ Yorùbá, kìí ṣe gbogbo ẹni tó bá ń jẹ́ orúkọ yìí ló jẹ́ ẹbí Adeleke, irọ́ ni ìròyìn tí àwọn ènìyàn ń gbé kiri pé gómìnà Adeleke kó àwọn ẹbí rẹ̀ sínú àwọn tó fẹ́ yàn sípò.”

Ilé aṣòfin Osun fàwọn orúkọ Kọmíṣọ́nà tí Adeleke fi ṣọwọ́ síwọn léde

Adeleke àti ilé aṣòfin Osun

Oríṣun àwòrán, COLLAGE

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun ti ṣe àgbéjáde àwọn orúkọ ènìyàn tí gómìnà Ademola Adeleke kọ ránṣẹ́ sí wọ́n tó fẹ́ yàn sípò kọmíṣọ́nà àti àwọn olùbádámọ̀ràn ní ìpínlẹ̀ náà.

Níbi ìjókòó ilé ní ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Keje oṣù Keje ni Abẹnugan ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun, Adewale Egbedun ló ka lẹ́tà kan tí orúkọ àwọn ènìyàn náà èyí tí gómìnà Adeleke kọ ránṣẹ́ sí etí gbogbo àwọn ọmọ ilé.

Egbedun ní àwọn máa ṣe àgbédìde ìgbìmọ̀ tó máa kọ́kọ́ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ náà ní abẹ́nú kí ilé tó tún wá ṣe ìdánwò fún wọ́n kí wọ́n tó buwọ́lù wọ́n.

Lára àwọn orúkọ tó wà nínú lẹ́tà gómìnà náà ni Agbẹjọ́rò Oladosu Babatunde, Ọmọọba Bayo Ogungbangbe, Sesan Epharaim Oyedele, Agbẹjọ́rò Kolapo Alimi, Soji Ajeigbe, Moshood Olalekan Olagunju, George Alabi, Sunday Olufemi Oroniyi, Abiodun Bankole Ojo, àti Dókítà Basiru Tokunbo Salami.

Àwọn mìíràn ni Morufu Ayofe, Sola Ogungbile, Ẹni ọ̀wọ̀ Bunmi Jenyo, Ayo Awolowo, Agbẹjọ́rò Wole Jimi Bada, Dipo Eluwole, Alhaji Rasheed Aderibigbe, Ọ̀jọ̀gbọ́n Morufu Ademola Adeleke, Adeyemo Festus Ademola, Olabiyi Anthony Odunlade, Agbẹjọ́rò Jola Akintola, Mayowa Adejori, Adenike Folashade Adeleke, Tola Faseru, àti Alhaji Ganiyu Ayobami Olaoluwa.

Ilé aṣòfin náà ti wá gbé ìgbìmọ̀ tí yóò kọ́kọ́ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ náà kalẹ̀ tí wọ́n sì ní kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn ní kíákíá.

Adeleke forúkọ àwọn kọmíṣọ́nnà ṣọwọ́ sílé àṣòfin báyìí- Olawale Rasheed

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Sẹ́nétọ̀ Ademola Adeleke ti fi orúkọ àwọn kọmíṣọ́nà àti àwọn olùbádámọ̀ràn tó fẹ́ yàn ṣọwọ́ sí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ náà.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Adeleke, Mallam Olawale Rasheed fi síta ló ti sọ̀rọ̀ náà.

Rasheed ní kété tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin bá ti wọlé padà láti ìsinmi tí wọ́n lọ fún ni wọ́n máa ka àwọn orúkọ náà síta fún àyẹ̀wò ló péye.

Lẹ́yìn tí wọ́n búra wọlé fún àwọn aṣòfin ọ̀hún ni wọ́n lọ fún ìsinmi láti gbáradì fún iṣẹ́ tó wà níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí aṣòfin

Agbẹnusọ gómìnà ọ̀hún nínú àtẹ̀jáde náà ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni àwọn aṣòfin náà máa padà sẹ́nu iṣẹ́ tí ìrètí sì wà pé abẹnugan ilé máa ka àwọn orúkọ náà sáwọn ọmọ ilé létí fún àyẹ̀wò nípa wọn.

“Gómìnà ti gbé ìgbésẹ̀ akin, tó sì ti ṣe ohun tó yẹ nípa fífi orúkọ àwọn tó fẹ́ yàn ṣọwọ́ sí ilé aṣòfin.”

Rasheed ní onírúurú àwọn nǹkan ló fa ìdádúró tó wáyé tí gómìnà kò fi tètè ṣe àkójọ àwọn orúkọ náà kó tó di àsìkò yìí.

“Lára àwọn nǹkan tó fa ìdádúró ni ẹjọ́ tí àwọn ẹgbẹ́ alátakò bá gómìnà fà, ètò ìdìbò gbogbogbo tó wáyé àtàwọn nǹkan mìíràn.”

“Ohun tó dára ni pé kò sí ìdádúró kankan mọ́ báyìí, ètò gbogbo ti parí láti yan àwọn kọmíṣọ́nà.”

Kí ló dé tí gómìnà Adeleke kò ṣe tíì yan àwọn kọmíṣọ́nà lẹ́yìn oṣù méje lórí ipò?

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Láti ìparí oṣù Kẹfa ọdún 2023 ni àwọn ènìyàn kan ti ń kùn pé tí a bá kà á ní ení, èjì, ó ti tọ́ oṣù méje tí gómìnà Ademola Adeleke ti gba ọ̀pá àṣẹ láti máa tukọ̀ ìpínlẹ̀ Osun fún ọdún mẹ́rin.

Ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni wọ́n búra wọlé fún Adeleke gẹ́gẹ́ bí gómìnà Osun lẹ́yìn tó fi ẹ̀yìn gómìnà àná, Gboyega Oyetola lulẹ̀.

Ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Keje ọdún 2022 ni ètò ìdìbò sípò gómìnà Osun wáyé tí àjọ elétò ìdìbò Nàìjíríà sì kéde pé Ademola Ademola tẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ló jáwé olúborí ìbò náà pẹ̀lú ìbò 403,371.

Gómìnà àná ní Osun, Gboyega Oyetola tó díje lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC tó ní ìbò 375,027 ni òun kò gbà èsì ìbò tó gbé Adeleke wọlé.

Lẹ́yìn ò rẹyìn, ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Supreme Court Kéde pé Ademola Adeleke ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, bí gómìnà Adeleke ṣe ti wọ ọ́fíìsì ni wọ́n ti ń fẹ́ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àyípadà ní ìpínlẹ̀ Osun pàápàá lórí yínyan àwọn Kọmíṣọ́nà tí yóò ba ṣe ìjọba.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ ń bèèrè pé kí ló dé tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn oṣù méje gẹ́gẹ́ bí gómìnà Osun, gómìnà Ademola Adeleke kò ì tíì yan Kọmíṣọ́nà kankan títí di àsìkò yìí.

Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí Agbẹnusọ gómìnà Adeleke, Mallam Olawale Rasheed láti mọ ohun tó ṣokùnfà tí gómìnà kò ì tíì fi yan kọmíṣọ́nà kankan, ó ní Adeleke ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yan àwọn kọmíṣọ́nà.

Gbogbo ìpèníjà tí ìjọba wa kojú ní ìbẹ̀rẹ̀ ni kò jẹ́ kí Adeleke tíì yan kọmíṣọ́nà

Rasheed ní gbogbo àwọn ìpèníjà tí ìjọba àwọn kojú nígbà tí àwọn gba ọ̀pá àṣẹ láti tukọ̀ ìpínlẹ̀ Osun wà lára àwọn nǹkan tó ṣokùnfà ìfàsẹ́yìn láti yan àwọn kọmíṣọ́nà.

Ó ṣàlàyé pé gbogbo bí àwọn ṣe ń ti ilé ẹjọ́ kan bọ́ sí òmíràn lórí ta ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò ṣe ìdádúró àwọn ìgbésẹ̀ kan tó yẹ kí ìjọba ti gbé.

Agbẹnusọ gómìnà náà wá sọ àrídájú rẹ̀ pé gómìnà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti yan àwọn kọmíṣọ́nà tí yóò ba ṣiṣẹ́ tó sì ti ń ṣe àkójọ àwọn orúkọ kan.

“Láìpẹ́, láì jìnà ni gómìnà máa fi orúkọ àwọn kọmíṣọ́nà ránṣẹ́ sí ilé aṣòfin.”

“Iṣẹ́ ti fẹ́ parí lórí àwọn tí wọ́n fẹ́ yàn gẹ́gẹ́ bí kọmíṣọ́nà, gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ ni ìjọba sì ti ń gbé báyìí.”

Ó fi kun pé ètò ìdìbò gbogbogbo tó wáyé ní Nàìjíríà náà wà lára ohun tó ṣe ìdádúrọ yíyan àwọn kọmíṣọ́nà náà di ìwòyí.

A ti ń san lára àwọn gbèsè tí ìjọba APC jẹ kalẹ̀ ní Osun

Rasheed tún tẹ̀síwájú pé pẹ̀lú bí gómìnà Ademola Adeleke kò ì tíì ṣe ní àwọn kọmíṣọ́nà tó ń ba ṣiṣẹ́, ó ní gudugudu méje àti yàyà mẹ́fà ni ìjọba àwọn ti gbé ṣe láti oṣù méje sẹ́yìn tí àwọn ti gba ìjọba.

Ó ní àwọn ti da ọ̀nà tó tó kìlómítà ọgbọ̀n lẹ́nu ìgbà tí àwọn ti gba ìjọba àti pé ọ̀nà oní kìlómítà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n mìíràn ń lọ lọ́wọ́.

Ó ṣàlàyé pé gómìnà Adeleke ti ṣèlèrí láti ṣe ọ̀nà kìlómítà ọgọ́rùn-ún ní ọdún àkọ́kọ́ lórí oyè gẹ́gẹ́ bí gómìnà Osun.

“Lórí ọ̀rọ̀ omi, gbogbo àwọn wọ́ọ̀dù 332 tó wà ní ìpínlẹ̀ Osun, jẹnẹrétọ̀ tó máa mú àwọn omi yẹn ṣiṣẹ́, wọ́n ti rà wọ́n.”

“Gbogbo ọ̀nà láti mú àwọn ìgbèríko dàgbà nípa iná, omi, ọ̀nà, gbogbo ẹ̀ là ń ṣe lọ́wọ́.”

“Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Osun báyìí, àwọn nǹkan tí kò ṣẹlẹ̀ rí ni, tí àwọn ará ìlú sì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”

Agbẹnusọ gómìnà náà tún ṣàlàyé pé gbèsè owó oṣù tí ìjọba àwọn jogún ni àwọn ti ń san àti pé àtúntò ti ń bá àwọn iléeṣẹ́ ìjọba.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Rasheed kò sọ pàtó iye oṣù pàtó tí wọ́n ti san gbèsè rẹ̀, ó ní ìjọba àwọn pín owó náà sì oṣù mẹ́ta mẹ́ta, tí àwọn sì ti san ẹ̀ẹmèjì níbẹ̀.

“Ìjọba wa ń san owó náà díẹ̀ díẹ̀ ni nítorí owó náà pọ̀, Osun ò lówó, àwọn ìjọba tó lọ ti balẹ̀ jẹ́.”