Ẹ̀ní tí a rò pé kò lè pàgọ́ tó kọ́lé alárinrin ní bí Adeleke ṣe borí Oyetola ní Osun– Olunloyo sọ̀rọ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Victor Omololu Olunlọyọ ti sapejuwe gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke gẹgẹ bi ẹni ti aye ropin amọ ti ori rẹ wa lẹyin rẹ.

Olunlọyọ sọ ọrọ yii lasiko ti Gomina Adeleke ṣe abẹwo sii ni ile rẹ ni ilu Ibadan, ni ipinlẹ Ọyọ.

O ni iyalẹnu ati ijọniloju lo jẹ fun awọn ti ko ṣatilẹyin fun Adeleke lori bi o ṣe gbe igba oroke.

Amọ gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ naa doju ti awọn ọta rẹ pẹlu bi o ṣe yọ gomina to wa nipo kuro, to si di ipo gomina naa mu.

‘’Adeleke, bawo lo ṣe ṣe, bawo lo sẹ bori ninu idibo naa?’’

‘’Iwọ ni ẹni ti gbogbo agbaye fi oju tẹnbẹlu, amọ iyalẹnu lo jẹ fun wọn nigba ti o gbe igba oroke gẹgẹ bi gomina. O nilo lati kọ mi ni awọn imọ ikọkọ ti o lo.

''Ko tan si bẹ, o tun bori ni ile igbimọ aṣofin agba, kekere, to fi mọ ile aṣofin ipinlẹ. Gbogbo agbaye lo ya lẹnu patapata.''

Gomina tẹlẹri naa ti awọn mọlẹbi rẹ naa pejọ sibẹ gboriyin fun Adeleke fun awọn igbeṣẹ to ti gbe lati igba to ti de ipo gomina.

Bakan naa ni wọn gbadura fun un pe yoo sẹ aṣeyọri.

Ninu ọrọ rẹ, Adeleke ni oun wa ṣe ayy ni ilu Ibadan ni ti oun si ya ki gomina ana naa.

Ninu fidio ti wọn fi si ori ẹrọ ayelujara ni awọn mọlẹbi ati ẹbi rẹ ti wa pẹlu rẹ ti Adeleke si wa nibẹ pẹlu.

Bakan naa ni wọn n ṣe awada nibẹ, ti wọn si n ranti awọn iwe akagbadun ti wọn ti ka nigba kan ri.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post