Àwọn afurasí ajínigbé yawọ ṣọ́ọ̀ṣì, pa pásítọ̀, jí èèyàn méje gbé lọ ní Ogun

Oríṣun àwòrán, Others
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn agbébọn kan yawọ ilé ìjọsìn ìjọ Redeemed Christian Church of God ti Omum Pepe ìpínlẹ̀ náà.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun, Omolola Odutola fi síta lọ́jọ́ Àìkú ọjọ́ Kejì oṣù Keje ọdun 2023 ní nǹkan bíi aago mẹ́rin àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Kìíní osù Keje ni ọ̀kan lára àwọn pásítọ̀ ìjọ náà, Pásítọ̀ Adesina Oyesegun mú ẹjọ́ wá sí àgọ́ ọlọ́pàá.
Odutola ní Pásítọ̀ Oyesegun ṣàlàyé pé ní nǹkan bíi aago mẹ́ta àbọ̀, lásìkò tí ìjọsìn ń lọ lọ́wọ́ ni àwọn jàǹdùkú kan tí wọ́n tó méje yawọ ilé ìjọsìn àwọn pẹ̀lú ìbọn, àdá àtàwọn ohun ìjà olóró mìíràn lọ́wọ́.
Ó ní bí wọ́n ṣe yawọ ilé ìjọsìn náà ni wọ́n ń yìnbọn sí gbogbo ibi tí wọ́n bá rí, tí wọ́n sì ń jí àwọn ọmọ ìjọ gbé.
Ó ṣàlàyé pé ìbọn tí wọ́n ń yìn yìí ba Pásítọ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pásítọ̀ Kayode Oluwakemi ní àyà tó sì kú ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀.
Odutola fi kun pé èyí ló mú kí àwọn ará ìlú àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó wà ní agbègbè náà kàn sí àwọn ìlú mìíràn tó wà ní agbègbè náà dọdẹ àwọn ajínigbé náà tí wọ́n sì kọjú ìjà sí wọn.
Ó ní gbogbo àwọn tí àwọn ajínigbé náà jí gbé ni wọ́n rí ìtúsílẹ̀ àti pé ìbọn ba ọ̀kan lára àwọn ajínigbé ọ̀hún tó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.
“A ti gbé òkú afurasí ajínigbé náà sí ilé ìgbókùúpamọ́ sí ní ilé ìwòsàn Owode Egba General Hospital.”
“Ìgbìyànjú ṣì ń lọ láti ṣàwárí àwọn afurasí ajínigbé yòókù tó fẹsẹ̀ fẹ.”
A gba àwọn ènìyàn tí àwọn ajínigbé náà fẹ́ jí gbé láì farapa - So-Safe
Ṣaájú ni ọ̀gá àgbà àjọ ẹ̀ṣọ́ ààbò So-Safe Corps, Soji Ganzallo ni àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ló gba àwọn tí ajínigbé náà jí gbé sílẹ̀.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ So-Safe, Moruf Yusuf fi léde ní àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn ní ẹ̀ka Owode-Egba ló gba ìpè pé àwọn ajínigbé jí àwọn ọmọ ìjọ náà gbé.
Yusuf ní àwọn gba àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láì farapa àti pé àwọn mú ọ̀kan nínú àwọn ajínigbé náà balẹ̀ tí ọ̀pọ̀ wọn sì farapa.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ̀ nìyí tí ìwà ìjínigbé ń wáyé ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pàápàá ní ilẹ̀ Yorùbá tó jẹ́ ẹkùn ìwọ̀ oòrùn gúùsù Nàìjíríà.
Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ajínigbé máa ń jí èèyàn gbé láti fi gba owó lọ́wọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí ẹni tí wọ́n bá jígbé.
Iye tí wọ́n máa ń bèèrè máa ń yàtọ̀ síra tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn máa ń san owó yìí kí wọ́n tó rí ìtúsílẹ̀.
Ìgbà mìíràn sì ni ẹlòmíràn máa ń pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àwọn ajínigbé yìí lẹ́yìn tí wọ́n bá san owó tán.
Ní bí ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni àwọn ajínigbé jí àwọn mẹ́ta kan gbé ní ìlú Iwo Isin, ìjọba ìbílẹ̀ Isin ìpínlẹ̀ Kwara.
Àwọn méjì nínú àwọn tí wọ́n jígbé yìí gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n san mílíọ̀nù márùn-ún náírà ti àwọn ajínigbé ọ̀hún sì pa ẹnìkẹta nítorí pé ó jẹ́ ọlọ́dẹ.















