Ẹ ri pé ẹ gba ife ẹ̀yẹ wálé níbi ìdíje àgbáyé - Tinubu sí Super Falcons

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Iyawo Aarẹ, Oluremi Tinubu tí gba awọn agbabọọlu obìnrin ilẹ wa, Super Falcons ni iyanju lati gba ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye lorilẹede Australia ati New Zealand.

O parọwa yii niluu Abuja nigba to n gba alejo awọn agbabọọlu ọhun lọjọ Satide, saaju igbadi ti wọn yoo morile fun idije naa ti yoo bẹrẹ ni ogunjọ oṣu keje si ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun 2023.

Tinubu, eni ti Dokita Betta Edu, olori obìnrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC ṣoju fun ni aṣeyọri ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons jẹ ọpọlọpọ ọmọ Naijiria logun ati pe ohun iwuri ni yoo jẹ ti wọn ba gba ife ẹyẹ naa wale.

O tẹsiwaju pe ere bọọlu lorilẹede Naijiria jẹ ọkan lara nnkan to n mu isọkan wa laarin awọn ọmọ Naijiria.

"O ṣe koko ki ẹ mọ pe iṣọkan yii le bori ohunkohun."

"Ti ẹ ba fọwọsowọpọ, aseyọri ni tiyin ninu idije yii, mo si ni igbagbọ pe ẹ maa fakọyọ ninu idije yii ju ti tẹlẹ lọ."

"O da mi loju pe gbogbo ọmọ Naijiria ni yoo ṣe atilẹyin fun-un yin. Ẹ jọọ ẹ sa ipa yín lati gba ife ẹyẹ agbaye naa."

Ṣáájú, Aarẹ ajọ to n ri si ere bọọlu, Alhaji Ibrahim Gashua dupẹ lọwọ ijọba apapọ fun atilẹyin ti wọn n ṣe fun ere idaraya.

"Ere bọọlu jẹ nnkan to n mu isọkan wa lagbaye.

"Mo rọ gbogbo awọn olukọni lati ṣe iṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ ki wọn le gba ife ẹyẹ naa."