Èèmọ̀! Ọ̀ọ̀nì ṣekúpa ọkùnrin kan tó sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ erin lákátabú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkunrin apẹja kan to sa asala fun ẹmi rẹ lọwọ awọn erin to pade lojiji ṣagbako iku ojiji lẹyin ti ọọni ṣekupa a.
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Zambia ṣalaye pe Ọgbẹni Dean Nyirenda n bọ pẹlu ọrẹ rẹ meji lati ibi ti wọn ti lọ pẹja lỌjọru ọsẹ to kọja nigba ti wọn sadeedee pade awọn erin lọna.
Bayii ni ọrọ di bo o lọ ya n mi, ti awọn mẹtẹẹta si fẹsẹ fẹẹ.
Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa ni ninu odo kan ti wọn n pe ni odo Luangwa ni Nyirenda bẹ si ti o si mukun ninu omi naa.
Ọga ọlọpaa Robertson Mweemba sọ fawọn akọroyin pe ninu odo yii ni ọọni ti bu Nyirenda jẹ ni itan rẹ ọtun.
Erin pọ ni orilẹede Zambia, ọpọ igba si ni ikọlu laarin erin atawọn eeyan ti waye ni bii ọdun meloo kan sẹyin eyi to ti gba ẹmi ọpọ eeyan.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe Nyirenda gbiyanju lati jaja bọ lọwọ ọọni lẹyin to fi igi kan to wa lọ rẹ lu ọọni ọhun.
Ọga ọlọpaa Mweemba sọ pe Nyirenda tiraka lati bọ si ebute omi lẹyin ti ọọni naa bu u jẹ tan.
Awọn akẹgbẹ rẹ meji yooku sare lọ ba a leti omi, wọn si gbe e digba digba pẹlu bi ẹjẹ ṣe n da lati oju ọgbẹ ibi ti ọọni ti bu u jẹ ni itan rẹ.
Ọga ọlọpaa ni wọn gbiyanju lati da ẹjẹ to n da silẹ duro, ṣugbọn Nyirenda pada jẹ Ọlọrun ni pe.
''Mẹẹdogun ninu eeyan mẹrindinlogbọn tawọn ẹranko pa ni Zambia lọdun 2023 ni ọọni ṣekupa''
Awọn oṣiṣẹ ọgba ẹranko ti wọn ṣabẹwo si ọkunrin naa ri apa eyin ọọni nibi to ti bu Nyirenda jẹ ni itan rẹ.
Mẹẹdogun ninu eeyan mẹrindinlogbọn tawọn ẹranko pa lọdun 2023 ni a gbọ pe ọọni ṣekupa.
Ọpọ ikọlu to mu ẹmi awọn eeyan naa lọ lo ṣẹlẹ ni odo Luangwa.
Ṣaaju ni ijọba orilẹede Zambia ti kilọ fawọn araalu atawọn arinrin-ajo afẹ wi pe ki wọn ṣọra lasiko ti wọn ba n rinrin ajo ninu igbo ẹranko orilẹede naa.
Awọn alaṣẹ igbo ẹranko ni Zambia ti n wa ọna lati dẹkun bi awọn ẹranko ṣe n sẹkupa awọn eeyan.
Lara nnkan ti wọn n gbero ni mimọ odi yika igbo ẹranko.



























