Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Plateau, ó ti mú ẹ̀mí mẹ́rin lọ

Aworan ekute to n fa aisan Lassa

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ipinlẹ Plateau ti jẹ ko di mimọ pe itankalẹ aarun iba Lassa ti n ṣe ikọlu si ijọba ibilẹ meje, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe eeyan mọkanla ti lugbadi iba naa, ti eeyan mẹrin mii si ti jade laye lati oṣu kejila ọdun 2025.

Kọmisana fun eto ilera nipinlẹ Plateau, Dokita Nicholas Baamlong, lo kede eyi nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Ṣatide ni ọfisi rẹ niluu Jos, nibi to si ṣalaye ni kikun ati igbesẹ ti ijọba n gbe lori itankalẹ aisan Lassa naa

"Wọn pe akiyesi wa si iṣẹlẹ yii ni Ogunjọ oṣu kejila ọdun 2025, nigba ti eeyan kan ko iba naa ni ijọba ibilẹ Quanpan, ti a si bẹrẹ igbesẹ oni kiakia."

Gẹgẹ bii kọmisana ṣe ṣalaye, ipinlẹ naa ti ṣe akọsilẹ pe eeyan mejidinlọgbọn, ti wọn si fi idi mẹfa ninu wọn mulẹ.

"Ni asiko naa, a se iwadii eeyan mọkandinlaadọrin, ti a si ṣe akọsilẹ eeyan mẹrindinlogun, ti a si fidi marun un mulẹ pe wọn iba Lassa.

"Eyi tu mọ si pe laaarin oṣu kejila si asiko yii, a ti ri eeyan mọkanla to ni Iba Lassa nipinlẹ Plateau," o sọ.

Kọmisana tun fikun pe itankalẹ iba yii ti ṣekupa eeyan mẹrin ni awọn ileeṣẹ nipinlẹ naa.

O tẹsiwaju pe ọkan lara eeyan to padanu ẹmi rẹ jẹ oṣiṣẹ eto ilera.

"O ṣe ni laanu pe, a ti ṣe akọsilẹ eeyan mẹrin to ti padanu ẹmi wọn, meji ni ile iwosan fasiti Jos, ọkan ni Plateau Specialist Hospital, ati ọkan ni Bingham University Teaching Hospital.

"Ọkan ninu awọn eeyan yii jẹ oṣisẹ ilera to da ọkan ninu awọn eeyan to ni iba lohun. Ni oni bayii, dokita kan wa ni idubulẹ aisan, to si n gba itọju," Dr Baamlong ṣalaye.

Baamlong ni eeyan 109 ni ijọba n ṣe ayẹwo fun bayii.

"Ohun ti a n ṣe bayii ni pe ki a tẹsiwaju ninu iwadii, ki a si ja fafa lati ma lọ si awọn agbegbe yii," o ṣo.

Awọn ijọba ibilẹ ti Iba Lassa yii ti de ni Quanpan, Shendam, Wase, Guusu Langtang, Ariwa Jos, Guusu Jos, ati Mangu.