Epo bẹntiróòlù máa tó pọ̀ síi ní Nàìjíríà- NNPC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ to n risi ọrọ pinpin epo bẹntiroolu kaakiri Naijiria ti ṣalaye pe ko si ootọ ninu pe epo máa wọn sii.
Wọn sọ pe dipo eyi iye ti awọn ọmọ Naìjiria maa ra epo maa dinku sii laipẹ.
Bakan naa ni Ajọ to n risi karakata epo bẹntirol ni Naijiria, IPMAN ti ni ko si otitọ ninu iroyin pe awọn fẹ fi owo kun owo epo bẹntirolu.
Saaju ni iroyin ti gbe pe wọn fẹ ṣe afikun owo epo bẹntirol si 700 naira nitori ọwọngogo dọla.
Eyi ko ṣẹyin bi aarẹ Tinubu ṣe fi aṣẹ si yiyọ owo iranwọ epo bẹntirol, to si tun pinnu pe ki idọgba wa laarin iye owo ti wọn n ra dọla ni banki ati awọn ibi ti kii ṣe banki tabi ile ifowopamọsi.
Ajọ Independent Petroleum Marketers Association of Nigeria(IPMAN) ati ajọ Distributors and Transporters of Petroleum Products (ADITOP) ni ko si ohun to jọ bẹẹ lati ọdọ wọn, wi pe iroyin ẹlẹjẹ ni.
Ṣé lóòtọ́ ni pé wọ́n tún fẹ́ ṣe àfikún owó epo bẹntirol sí N700?
Lasiko ti wọn n ṣe ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria, NAN ni wọn fi ọrọ naa lede.
Ajọ naa ni iye ti wọn n ta epo ti bẹrẹ sini ṣe deede ni oju ọja nitori naa wọn ko nilo lati ṣe afikun owo epo bẹntirol.
Saaju ni wọn ti ni iye owo epo naa n ṣe segesege nitori owo naira ti o fidi rẹmi si owo ilẹ okeere.
Gẹgẹ bi iroyin ti ileeṣẹ NAN gbe jade, awọn oniṣowo kan ni Naijiria ni oṣeeṣe ki owo epo lọ si oke de 700 naira ju 540 naira ti wọn n ta lọwọlọwọ ni ni awọn agbegbe kan ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @Others
Wọn ohun gbogbo yoo rọrun fun awọn araalu ni wẹrẹ ti awọn elepo ba ti bẹrẹ si ni gbe epo wọle si Naijiria lati Osu Keje ti a wa yii.
Iye jaala epo ni wọn ṣalaye pe o niise pẹlu iye ti naira jẹ loju ọja ati iye ti wọn fi n gbe epo wọle si orilẹede Naijiria.
N769.25 naira ni wọn ta iye owo dola si owo Naijiria ni Ọjọ Ẹti ni oju ọja idokowo, eleyii to mu ki owo naira tun lọ silẹ si ju 763 naira ti wọn ta lasiko ọdun Sallah.

















