Ṣé lóòtọ́ ni pé kò sí ewu nínú rírọ afẹ́fẹ́ gáàsì sínú ẹ̀rọ amúnáwá ‘generator' rẹ? Àlàyé rèé

Gaasi ati ẹrọ amunawa

Oríṣun àwòrán, SANDRA MICHAEL FACEBOOK

Lati igba ti ijọba Naijiria ti kede pe oun yoo yọ owo iranwọ ori epo bẹntiro ni iye owo ti wọn n ta epo ọhun ti fo si ilọpo mẹta.

Ọjọ kan lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu kede igbesẹ naa ni owo epo ti fo lati ₦‎198 si ₦‎537 ni ọpọ ile epo kaakiri Naijiria.

Eredi ree ti ọpọ ọmọ Naijiria ṣe n wa awọn ọna miran lati maa lo ẹrọ amunawa ‘generator´ wọn lai lo epo bẹntiro.

Lara awọn ọna ti awọn eeyan kan n wa ni lati lo afẹfẹ gaasi lati mu ina jade ninu ẹrọ amunawa wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Njẹ o ṣeeṣe lati lo afẹfẹ gaasi idana ninu ẹrọ amunawa ‘generator?’

Ileeṣẹ iroyin BBC kan si awọn onimọ nipa ina mọnamọna ati afẹfẹ gaasi, wọn si fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni eeyan le lo afẹfẹ gaasi ninu ẹrọ amunawa.

Uche Chieke, to jẹ onimọ nipa ọpa epo sọ pe eroja ‘methane’ lo wa ninu gaasi idana eyii to ṣeeṣe ko ṣiṣẹ ninu ẹrọ amunawa.

Ẹlomiran to tun jẹ onimọ nipa epo bẹntiro, Ejie Kemkanma ṣalaye fun BBC pe nipa imọ ẹrọ, o ṣeeṣe lati lo gaasi ti wọn fi n dana lati fa ina si ara awọn ẹrọ kan.

O fi kun pe iye owo ti eeyan yoo na lori gaasi naa ko pọ iye owo ti eeyan yoo na lori epo bẹntiro.

Irufẹ ewu wo lo wa ninu lilo afẹfẹ gaasi pẹlu ẹrọ amunawa ‘generator?’

Wayi o, ọpọ eeyan lo ti n bere pe ṣe o lewu lati maa lo gaasi pẹlu ẹrọ amunawa.

Ninu ọrọ rẹ, Uche Chieke ṣalaye fun BBC pe ko si ewu kankan ninu lilo afẹfẹ gaasi fun ẹrọ amunawa, niwọn igba ti gaasi naa ko ba ti jo danu.

Onimọ miran, Patrick Chidozie Ezenachi sọ pe gaasi idana jẹ ọkan lara awọn gaasi to dara ju ti kii ṣe akoba fun ayika kaakiri agbaye.

Amọ Ejie Kemkanma, to tun jẹ onimọ miran nipa gaasi ati epo rọbi ni bo tilẹ jẹ pe gaasi dara lati lo, awọn eeyan gbọdọ sọra gidi nitori ibugbamu.

Wayi o, ti o ba fẹ maa lo gaasi pẹlu ẹrọ ‘generator’rẹ, o gbọdọ tọ awọn akọṣẹmọṣẹ atawọn to ni imọ nipa rẹ lọ lati ba ọ ṣe tabi tọ ọ sọna.