Kìí ṣe torí àwọn ọmọ Nàìjíríà la ṣe dáwọ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa mú ẹbí dání wá kàwé dúró! – ìjọba UK

Oríṣun àwòrán, Others
Aṣojú orílẹ̀ èdè United Kingdom sí orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Richard Montgomery ní ìpinnu UK láti ṣe ìdádúrò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ òkèrè láti máa kó àwọn ẹbí wọn dání kìí ṣe nítorí àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Montgomery ní ìgbésẹ̀ náà tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2024 jẹ́ láti dá ààbò bo àwọn ohun amáyédẹrùn orílẹ̀ èdè náà nítorí àwọn ènìyàn tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ ń kó wọn orílẹ̀ èdè náà ti pọ̀ púpọ̀ jù.
Níbi ìpàdé kan tí Montgomery ṣe pẹ̀lú igbákejì ààrẹ Nàìjíríà, Kashim Shettima ní Abuja ló ti sọ̀rọ̀ náà.
Ó ní iye àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní UK ti lékún púpọ̀ gan ní ìlọ́po márùn-ún àti pé bẹ́ẹ̀ náà ló rí pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń wá láti orílẹ̀ èdè mìíràn.

Oríṣun àwòrán, ChannelsTV
Ó fi kun pé nǹkan ńlá ló jẹ́ fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga àwọn bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń wá káàkiri ilẹ̀ òkèrè àmọ́ ó ṣòro láti pèsè ilé ìgbé àtàwọn ohun amáyédẹrùn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń wá pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn.
Nínú oṣù Karùn-ún ọdún yìí ni ìjọba UK kéde pé àwọn máa dènà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti máa mú àwọn ẹbí wọn wọ orílẹ̀ èdè àwọn lójúnà àti dènà lílo ọ̀nà yìí láti fi máa ṣiṣẹ́ lọ́nà àìtọ́.
Montgomery sọ àfikún rẹ̀ pé lọ́dún 2022, físà mílíọ̀nù mẹ́ta ni UK fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ilẹ̀ òkèrè ní èyí tí àwọn ọmọ Nàìjíríà jẹ́ 325,000 nínú wọn.
Ó ní èyí fi hàn pé Nàìjíríà kó ohun tó kọjá ìdá mẹ́wàá nínú àpapọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lọ ń kàwé ní London àti UK lápapọ̀.
Ó sọ àfikún rẹ̀ pé kìí ṣe nítorí àwọn ọmọ Nàìjíríà ni àwọn fi gbé ìgbésẹ̀ náà bíkòṣe láti ṣe àmójútó àwọn ohun amáyédẹrùn tí àwọn le pèsè fún wọn.















