Iye ìgbà táwọn ọmọ Nàìjíríà ti dà ẹbí nǹkán tó sọnù ru àwọn ẹranko

A ti rin jina a si ti ri abuke ọkẹrẹ ṣugbọn ejo to n gbe owo mi tabi aja to n gbe ibi ọmọ jẹ?
Awọn nkan wọnyii ṣe wa ni haahin to si da wa loju pe ẹyin naa yoo ṣe kayeefi lori rẹ.
Ninu iroyin wa kan taa gbe laipẹ yi la ti jabọ pe awọn oṣiṣẹ ile iwosan kan ni ilu Emure n'ijọba ibilẹ Owo, nipinlẹ Ondo ko si panpẹ ọlọpaa lẹyin ti wọn ko le pese ibi ọmọ kan ti wọn bi si ile iwosan naa.
Ohun iyalẹnu ni pe awọn ti wọn fẹsu kan yi sọ pe aja lo gbe ibi ọmọ naa jẹ.
Wọn ko ti ri aja naa bẹẹ́ si ni kosi ẹni to mọ ibi ti ibi ọmọ naa ha si.
Awọn ti wọn fẹsun yi kan ṣi wa ni ahamọ ọlọpaa ṣugbọn ki wọn to yanju ọrọ lori ibi ti ọrọ yoo ja si, a ni ki a ṣe akojọpọ awọn iroyin kayteefi mii to niṣe pẹlu bi awọn eeyan ti ṣe di ẹbi nkan ini to sọnu ru awọn ẹranko.
Ejo gbe owo ajọ idanwo JAMB mi ni Naijiria

Philomina Chieshe lorukọ oṣiṣẹ ajọ to n mojuto idanwo igbaniwọle si ile ẹkọ fasiti ni Naijiria, JAMB ti iroyin yi da lori rẹ.
Ni ọdun 2018 ni o kawọn pọnyin rojọ lori ẹsun irọ pipa ti ajọ JAMB fi kan an.
Nigba ti arabinrin yi de iwaju ajọ to n gbogun ti iwa jẹguduj ra EFCC o sọ ọrọ kabiti kan ti o mu ki gbogbo eeyan maa ṣe eemọ.
O ni ọrọ ko ri bẹ pe oun parọ ibi ti owo wa bi kii ṣe pe ejo gbe owo 36miliọnu ti wọn lo sọnu naa mi.
Ọrọ yi jọ bi ere ṣugbọn lẹyin ọpọ iwadii, o pada jẹwọ pe ọga rẹ lọfisi Samuel Sale Umoru to jẹ adari ajọ Jamb lo gba owo naa lọwọ oun.
Inaki gbe owo to fẹẹ to 7 miliọnu mi ni Kano

Oríṣun àwòrán, JOHN MACDOUGALL
Oṣu Kẹfa ọdun 2019 ni iṣẹlẹ eleyi naa waye ni ilu Kano.
Nigba naa lọhun, ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori bi owo to sunmọ miliọnu meje Naira ti ṣe poora ni ile ikẹrankopamọ si ni ilu Kano.
Agbẹnusọ ọlọpaa DSP Abdullahi Haruna sọ fun akọroyin BBC pe lootọ lowo yi poora.
O ni owo ti wọn pa lasiko tawọn eeyan ṣe abẹwo si ibudo ikẹrankopamọ si yi lasiko ọdun Ileya ni owo ọhun.
O sọ pe ''Ni bayi a ti mu awọn oṣiṣẹ ile ikẹrankpamọ si yi mẹwaa ti wọn si wa ni ahamọ ẹka iwadii ọlọpaa''
Ibeere tawọn ọlọpaa n beere lọwọ awọn oṣiṣẹ yi ni pe ki lo de ti wọn ṣe kọ lati ko wo ti wọn pa lọ si banki lẹyin ọjọ mẹfa.
Amọ ninu iroyin kan ti Ileeṣẹ iroyin Freedom Radio gbe soriu afẹfẹ nigba naa wọn ni ọkan ninu awọn oṣiṣẹ akawo ile ikẹrankopamọ si naa sọ fun awọn agbofinro pe inaki lo jẹ owo tawọn n wa ọhun.
Nigba ti BBC beere lọwọ alukoro ọlọpaa nipa iroyin yi, o ni awọn ko gbọ nkan to jọ bẹẹ ati pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ naa.
Kayeefi! Ọmọ dawati ninu posi oloyun to ku niluu Akure

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ẹ ko ba gbagbe, BBC Yoruba ṣe iroyin kayefi kan nigba diẹ sẹyin lasiko ti ariwo sọ ni ilu Akure, ipinlẹ Ondo pe obinrin kan fẹ bimọ o si gba ibẹ ku.
Nigba ti wọn ti bábá gbe oku sinu posi ti wọn ti n lọ si ibi ti wọn ti fẹ sin in si ni ọkọ ronu to si ni oun tun fẹ ri oju iyawo oun ati oku ọmọ.
Idi ni wipe awọn nọọsi gbẹbi ọmọ naa lootọ lati gbe e jade ninu iya rẹ to ti ku ṣugbọn ọmọ ọhun naa ti ku ki wọn to gbe e jade.
Ẹwẹ, nibi eto isinku, ọkọ wo oju iyawo rẹ fun igba ikẹhin ninu posi amọ ṣe lo tun ni oun fẹ wo oku ọmọ ti wọn gbe sinu ọra lẹgbẹ iya rẹ.
Nigba ti wọn yoo tu ọra naa, ko si oku ọmọ ninu rẹ, oriṣiriṣi nnkan mii ni wọn ko sinu rẹ, ariwo ba sọ.
Ọrọ naa di ọrọ ọlọpaa lasiko naa tori arakunrin naa ni oun ko ni gba ayafi ki wọn ti ọwọ ofin bọ ọrọ naa.
Naijiria nikan kọ, iṣẹlẹ mii waye ni Burundi
Iṣẹlẹ miran to jọọ iru awọn eyi taa ka silẹ yi waye lorilẹede Burundi sugbọn oogun abẹnu gọngọ ni wọn di ẹbi iṣẹlẹ yii ru.
Boya ni o tilẹ ti gbọ nipa owo anabọ ri? Eleyii lo farahan ninu iroyin yii bi o tilẹ jẹ wipe o fara jọ iroyin ejo akowomi lorilẹede Naijiria, sugbọn owo anabọ ni ohun jẹ.
Iṣẹlẹ yii waye ni ile ifiweranṣẹ alabọde kan to wa ni agbegbe Cibitoke ni iwọ oorun orilẹede Burundi.
Gẹgẹbi iroyin ti ṣe sọ, ọkunrin kan wọ ileefiweranṣẹ naa pẹlu owo beba ẹgbẹrun mẹwa (eyi ti yoo jọ nkan bii ẹgbẹrun meji abọ naira) o si n beere fun iyoku owo rẹ.
Agbowo ileefiweranṣẹ naa ko owo ti arakunrin yii mu wa pẹlu awọn owo miran to wa ni aapo ileeṣẹ naa.
Amọṣa, nigba ti yoo fi yẹ owo naa wo pada, gbogbo miliọnu mẹtalelogun owo ilẹ Burundi (ti yoo ja si miliọnu meji naira o le diẹ) to wa nibẹ ti poora pẹlu owo ti arakunrin yii mu wa.
Bakannaa ni wọn ni arakunrin to mu owo ọhun wa pẹlu ti poora lẹyẹ o sọka.
Alukoro ileesẹ ọlọọpa lorilẹede naa fi idi isẹlẹ yii mulẹ to si ni awọn ọkunrin meji ni wọn ti fi si ahamọ lori ọrọ naa titi di igba ti iwadi yoo fi pari.












