BBC tú àṣírí àwọn tó ń fìyà jẹ ọ̀bọ láti fi pa owó

monkey torture

Iwadii ọlọdun kan ti ileeṣẹ iroyin BBC ṣe ti tu aṣiri bi awọn eeyan kan ṣe n mọọmọ fi iya jẹ ọbọ lọna aitọ.

Iwadii wa fihan pe ogunlọgọ awọn eeyan lati ilẹ Gẹẹsi, Amẹrika ati Indonesia lo n san owo lati wo fiimu bi wọn ṣe n pa ọbọ ni ipakupa.

Oju opo YouTube lawọn ti wọn n fi iya jẹ awon ọbọ naa ti kọkọ si n ṣafihan rẹ ki wọn to lọ sori ikanni Telegram.

Ọlọpaa ti n wa awọn eeyan naa bayii, ọwọ si ti tẹ diẹ lara wọn.

Akọroyin BBC to wa loju opo Telegram naa jabọ pe oju opo ọhun lawọn eeyan ti maa n daba bi wọn ṣe n fẹ ki wọn fiya jẹ awọn ọbọ ti wọn si gbadun lati maa wo fọran irufẹ iwa bẹẹ.

Ko din ni ogun eeyan ti iwadii n lọwọ lori wọn bayii kaakiri agbaye latari ọrọ ọhun.

Oniṣiwo fiimu kan nilẹ Gẹẹsi, Mike McCartney, ti apẹle rẹ n jẹ "The Torture King" ṣalaye fun BBC pe iyalẹnu lo jẹ fun oun pe awọn eeyan kan le fẹran lati maa wo fọran bi wọn ṣe n fi iya jẹ ẹranko lainidi.

O ni ṣe lawọn eeyan ọhun maa n dibo lati yan irufẹ iya ati iku ti wọn n fẹ ki awọn ọbọ naa ku.

Ni Indonesia, ọlọpaa ti mu afurasi meji Asep Yadi Nurul Hikmah ati M Ajis Rasjana, ti awọn mejeji si ti fi ẹwọn jura.

monkey torture

Oríṣun àwòrán, ED OU/BBC

Nilẹ Amẹrika, iwadii ti n lọwọ lori afurasi meji, Stacey Storey ati ẹnikan ti a ko le darukọ amọ ti apẹle rẹ n jẹ “Mr Ape.”

“Mr Ape” ṣalaye fun BBC pe oun ti pa o kere tan, ọbọ mẹrin, oun si ti fi iya ija ọpọlọpọ ọbọ.

Ẹwẹ, oniruru fidio ifiyajẹni ọbọ lo kun oju opo Telegram ati Facebook ninu iwadii BBC.

Wayi o, ileeṣẹ Facebook ti sọ pe oun ti bẹrẹ si n ti oju opo eyikeyi to ba ṣafihan bi wọn ṣe n fi iya jẹ tabi ṣe iku pa ọbọ nitori oun ko fọwọ si ifiyajẹ ẹranko lọna aitọ.