Ó ń ṣe mí bíi kìnìún tó ń bú ramúramù láti pa àwọn ọ̀daràn tó ń dàmú Nàìjíríà jẹ - Kayode Egbetokun

Igbakeji aarẹ Shettima n de fila fun ọga ọlọpaa tuntun Kayọde Ẹgbẹtokun

Oríṣun àwòrán, Bashirahmad/twitter

Ọga ọlọpaa tuntun lorilẹede Naijiria, Kayọde Ẹgbẹtokun ti ṣalaye wi pe nṣe lo n ṣe oun bi kiniun to n bu ramuramu lati fi gbogbo awọn ọdaran to n da Naijiria laamu jẹ.

Ọga ọlọpaa Ẹgbẹtokun sọrọ yii lasiko to fi n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ti igbakeji aarẹ Kasim Shettima fi okun irawọ ipo rẹ tuntun kọ ọ lapa lọjọ Iṣẹgun.

Lalẹ ọjọ Aje ni Aarẹ Bọla Tinubu yan Ẹgbẹtokun atawọn ọgagun miran gẹgẹbi adari tuntun fun ẹka ileeṣẹ abo gbogbo lorilẹede Naijiria.

Ẹgbẹtokun ni ohun to kun oun ninu bayii ni igbaradi lati gbogun ti gbogbo awọn eeyan to ba fẹ da ọrọ abo ẹmi ati dukia lorilẹede Naijiria laamu.

“Ti mo ba ni ki n sọ bi o ṣe ri ni inu mi bayii, maa sọ pe, o n ṣe mi bii pe ẹkun kan wa ni inu mi to ṣetan lati le gbogbo awọn ọdaran kuro lorilẹede Naijiria.

“Ni igba miran, o n ṣe mi bii kiniun to ṣetan lati pa gbogbo awọn ọta Naijiria jẹ.”

Ṣáà ní, ọba mẹ́wàá ìgbà mẹ́wàá -Baba Usman, ọga ọlọpaa to n fi ipo silẹ

Ọga ọlọpaa tẹlẹ Baba Usman ati ọga ọlọpaa tuntun, Kayọde Ẹgbẹtokun

Oríṣun àwòrán, tvc

Ṣaaju ni ọga ọlọpaa to n fi ipo silẹ, Usman Baba ti kan sara si ẹni ti aarẹ ṣẹṣẹ yan sipo naa nitori pe ni iwoye rẹ, ẹni ti o kun oju iwọn iṣẹ naa ni.

Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ nileeṣẹ aarẹ Naijiria, Aso Rock Villa nilu Abuja, Ọga ọlọpaa Baba Usman ni ọba mẹwaa igba mẹwaa ni ile aye, inu oun si dun pe ẹni ti oun ati ẹ jọ dagba lẹnu iṣẹ naa ni ọpa aṣẹ naa bọ si lọwọ.

“A jọ dagba pọ lẹnu iṣẹ yi ni. Mo fi awn igba kan jẹ ọga rẹ, koda ki n to de ipo ọga agba ọlọpaa; igba meji ọtọọtọ lo ṣiṣẹ labẹ mi. Mo is mọ pe o le gbe opo iṣẹ ọlọpaa ga.”

Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá tuntun, IGP Kayode Egbetokun

IGP Kayode Egbetokun

Oríṣun àwòrán, Prince Olumuyiwa Adejobi

Aarẹ Bola Tinubu ti kede awọn alabaṣiṣẹ, awọn olori ileeṣẹ omọ ogun ati amugbalẹgbẹ tuntun.

Lara awọn eeyan naa ni awọn olori ileeṣẹ ọmọ ogun ati ọlọpaa.

Lara awọn olori eto abo tuntun ti Aarẹ ṣẹṣẹ yan ni Mallam Nuhu Ribadu, Maj. Gen. C.G Musa, Maj. T. A Lagbaja ati bẹẹ lọ.

Orukọ ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa tuntun ti Aarẹ Tinubu kede ni IGP Kayode Egbetokun.

Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Kayode Egbetokun ree

  • Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan an, ọdun 1964 ni wọn bi Kayode Egbetokun ni ijọba ibilẹ ila oorun Egbado, nipinlẹ Ogun.
  • O darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa lọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 1990.
  • Egbetokun kawe gboye nipa imọ iṣiro ni UNILAG, o tun kawe siwajuj nipa imọ ẹrọ ni UNILAG kan naa.
  • Lati ibẹ lọ, o kawe ni fasiti ijọba ipinlẹ Delta, fasiti Al-hikmah niluu Ilorin, Jos, UK, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
  • Egbetokun ṣiṣẹ lawọn ọọfisi ileeṣẹ ọọpaa kaakiri Naijiria lawọn ipinlẹ bii Eko, Osun, Zamfara, Kwara ati Abuja.
  • O ti fi awọn akoko igba kan ṣiṣẹ gẹgẹ bii kọmiṣọna ọlọpaa ni Eko, Kwara ati Abuja ri.
  • O tun ṣiṣẹ gẹgẹ bii igbakeji ọga ọlọpaa ni ẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran ni olu ọọfisi ọlọpaa to wa ninu Abuja.
  • Egbetokun fẹran ati maa kawe, ere idaraya bọọlu ẹlẹyin ati bọọlu alafẹsẹgba.
  • O fẹran ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, o si ni iyawo atawọn ọmọ.