Obìnrin ẹni ọdún 57 kó sí kàǹga ní Ilorin, pàdánù ẹ̀mí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE
Iléeṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara ni àwọn rí òkú obìnrin kan, Jamiu Sikirat yọ nínú kàǹga ní ìlú Ilorin, òlú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara.
Obìnrin ọ̀hún láti agbolé Ile-Agunko, agbègbè Adeta ní ìjọba ìbílẹ̀ Ilorin West jábọ́ sínú kàǹga ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kẹfà ọdún 2023.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ panápaná Kwara, Hassan Adekunle fi léde ní ìyá náà lọ pọn omi nínú kàǹga kó tó di wí pé ẹsẹ̀ rẹ̀ yọ̀ tó sì kó sínú kàǹga náà.

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE
Adekunle ṣàlàyé pé ará àdúgbò náà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Muhammad Jamiu ló pe àwọn láti fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn létí.
Ó ní nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn fi máa débẹ̀ láti dóòlà ìyá náà kúrò nínú kàǹga, òkú rẹ̀ ni àwọn rí yọ.
Ó fi kún un pé lẹ́yìn tí àwọn rí òkú náà yọ tán, àwọn gbé òkú ọ̀hún fún ọ̀kan lára mọ̀lẹ́bí ìyá náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alfa Abdulganiyu Akuko fún ètò ìsìnkú tó péye.
Bákan náà lọ ní àwọn ọlọ́pàá wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún lásìkò tí àwọn fi yọ òkú obìnrin ọ̀hún tí àwọn sì fi fa òkú rẹ̀ lé àwọn ẹbí rẹ̀ lọ́wọ́.
Adekunle ní adarí iléeṣẹ́ panápaná Kwara, Falade John Olumuyiwa bá àwọn ẹbí obìnrin náà kẹ́dùn tó sì tún rọ gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà láti máa ṣe jẹ́jẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ oòjọ́ wọn.














