Trinity Guy: Kí ni gbajúmọ̀ apanilẹ́rìín oní "prank" yìí ṣe tí Ọlọ́pàá ní ó yẹ kí wọ́n fòfin gbé e?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi ti sọ̀rọ̀ pe o yẹ ki ọlọpaa lọ fi ofin gbe gbajugbaja apanilẹrin to maa n tan eeyan jẹ ninu awọn fidio rẹ, Abdullahi Maruf ti ọpọlọpọ mọ si “Trinity Guy”.
Lootọ, ko farasin fun gbogbo awọn olulufẹ Trinity Guy pe awada ati itanjẹ rẹ maa n le gan to si maa n kọja nnkan to yẹ keeyan fi ṣere amọ pẹlu eyi, wọn n gbadun gbogbo fidio rẹ gan.
Trinity Guy funrarẹ ninu fidio ifọrọwanilẹwo rẹ pẹlu BBC Yoruba ti gba awọn to fẹ maa ṣe iru iṣẹ ti o n ṣe yii nimọran lati ma dan an wo rara tori oun yatọ si wọn.
Nigba miran, iroyin ni pe itanjẹ (prank) ti Trinity Guy n ṣe maa n fa idamu fun omii lara awọn to lọ ba.

Ki ni CSP Muyiwa Adejobi ri to fi da si ọrọ Trinity Guy?
Ẹwẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijria ti da gudugbẹ ọrọ silẹ laarin awọn ọmọ Naijiria lori ayelujara lẹyin to sọ ọrọ sita pe ṣe lo yẹ ki wọn lọ fi ofin gbe apanilẹrin naa.
Loju opo ayelujara rẹ, CSP Adejobi fi ọrọ sita nipa fidio kan ti Trinity Guy ṣe to si ero rẹ han nipa rẹ ninu akọle to kọ sori fidio naa.
“Ki gbogbo eeyan ti o ti fi ina awọn itanjẹ naa ra ara, tabi ti o ti ko ibẹru si wọn lọkan maa lọ fi ẹjọ sun toripe iwa ọdaran ni ọpọlọpọ “prank” wọn to si jẹ iwa aitọ ati iwa ibi. Awọn obinrin yii ni aridaju ẹsun lọwọ daadaa lati fi tako ọkunrin oni “prank” yii.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ diẹ sẹyin ni Adejobi fi ọrọ ikilọ sita fun awọn to fi intanijẹ ṣe fidio apanilẹrin pe ki wọn maa fi ọgbọn inu ṣe oniruuru fidio ti wọn ba n ṣe tori pe wọn n fi ẹmi awọn ọmọ Naijiria wewu.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Lọjọ Aje lo wa fi ọrọ sita to si ni pe o yẹ ki wọn fi panpẹ ofin mu Trinity Guy.
O wa rọ gbogbo eeyan ti awọn “prank” naa ti ṣe akoba fun pe ki wọn lọ fi ẹjọ wọn sun awọn alaṣẹ to si ni “iwa yii ti awọn apanilẹrin oni “prank” n hu ko boju mu rara. Mo roo pe o yẹ ki wọn ti mu arakunrin naa.”
Awọn itanjẹ kan wa ti Moruf ti ṣe to ni agbara gan to jẹ wipe o ti ko o si wahala.
Koda, o ti jẹ igbati, ifọti, ifọmu, igbaju. Wọn ti lu u bii bara to ba ara rẹ nileewosan ri.
Ninu fidio ifọrọwanilẹnuwo BBC Yoruba pẹlu Trinity Guy, o ni:

Oríṣun àwòrán, OTHERS
"Awọn "prank" kan wa ti mo ṣe to jẹ wipe ko dẹrun rara, koda ohun ti oju mi ri ko le jẹ ki n fi si ori ayelujara".
Moruf ni oun maa n jẹ iya gidi gan to jẹ pe “wọn na, na, lai la ilala Muhammadu rọ sulu lah”, nigba to fi di ọjọ keji, ile iwosan ni mo ti ba ara mi”.
Trinity tun ṣalaye pe ibẹta ni oun ti awọn mẹtẹta si jọ maa n lọ ṣe ere ori itage nigba ti wọn wa nile ẹkọ ibẹ si ni awọn mẹtẹta ti ri orukọ to n jẹ “Trinity Guy” eyi to tumọ si mẹtalọkan.
Ọpọlọpọ iṣẹ lo ni oun ti danwo amọ ti ko fibẹẹ pa owo wọle ayafi igba to ronu titi to si rii pe ti oun ba n ṣe itanjẹ, o lee ta gidi gan.
Bakan naa o gba awọn eeyan to ba fẹ maa ṣe “prank” bii tirẹ nimọran wipe ki wọn ma dan an wo rara tori pe nnkan ti oun n ṣe ti yoo jẹ lee ma jẹ bẹẹ fun awọn.
O maa n tọrọ aforiji lẹyin ti wọn ba ti ṣe fidio naa tan ti yoo si fun wọn ni owo.
Nnkan mẹfa ti ẹ ko mọ nipa Trinity Guy ree

Oríṣun àwòrán, OTHERS
- Abdullahi Maruf Adisa gangan ni orukọ rẹ, ọmọ bibi ilu Ibadan si ni to si tun kawe ni ilu Ibadan.
- Ọkan lara ibẹta ti awọn obi rẹ bi ni Trinity Guy jẹ ti wọn si jẹ bẹrẹ iṣẹ apanilẹrin lori itage pẹlu obinrin to wa laarin wọn.
- Trinity Guy ti ṣiṣẹ oniruuru ri, o ti ṣe akọni ni ere idaraya (Gym Instructor)
- Lọdun 1990s ni oṣu kọkanla ni wọn bi Trinity Guy gẹgẹ bi oun funra rẹ ṣe sọ amọ ko tii pe ọgbọn ọdun ni asiko ti iroyin yii jade
- Ọdun 2019 ni o bẹrẹ iṣẹ apanilẹrin to si di gbajumọ lasiko ajakalẹ arun Covid-19 ni Naijiria.
- Iroyin ni iwọn iye ti owo rẹ to ni ẹgbẹrun lọna aadọta Dollar.












