Torí ìfẹ́ àwọn ìbejì ni mo ṣe kọ̀ láti sọ ohunkóhun láti ọjọ́ yìí - Damola Olatunji

Damola Olatunji

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Ọjọ́ Kéjìdínlógún oṣù Kẹfà ọdọọdún jẹ́ àyájọ́ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ ní àgbáyé láti máa fi ṣe kóríyá fún àwọn bàbá lórí iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn ọmọ àti ẹbí wọn lápapọ̀.

Ní àyájọ́ ọjọ́ yìí, onírúurú ọ̀rọ̀ ìwúrí ni àwọn ènìyàn máa ń kọ láti fi ṣe ìmọrírì ara wọn tàbí àwọn ènìyàn tó bá sún mọ́ wọn.

Oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ìwúrí ni àwọn ènìyàn kọ sórí ìtàkùn ayélujára wọn lọ́jọ́ Àìkú tí àyájọ́ bàbá tí ọdún 2023 bọ́ sí bẹ́ẹ si ni gbajugbaja oṣere tiata, Damola Olatunji náà kọ tirẹ̀ àmọ́ ọ̀nà tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ fi gbà á ju ọ̀rọ̀ tó kọ síta lọ.

Gbajúgbajà onítíátà òséré tíátà náà kò gbẹ́yìn láti dá sí ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ yìí nígbà tó fi fídíò òun àti àwọn ìbejì tí gbajúmọ̀ òṣèré, Bukola Awoyemi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Arugba bí fún-un síta.

Ohun tí Damola Olatunji kọ ni pé ọ̀pọ̀ omijé bàbá àti ìbẹ̀rù rẹ̀ ni àwọn ènìyàn kìí rí.

Ó ní ọ̀pọ̀ bàbá ni kò mọ bí wọ́n ṣe ń fi ìfẹ́ hàn àmọ́ èyí kò túmọ̀ sí pé kó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀.

Ó fi kun pé ìkẹ́ àti ààbò bàbá ni igi lẹ́yìn ọgbà tó máa ń gbé ẹbí àti àwọn ọmọ rẹ̀ dúró.

Lẹ́yìn náà ni Damola ní ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí òun ní fún àwọn ìbejì òun ni kò jẹ́ kí òun sọ ohunkóhun nípa àwọn nǹkan tó ti ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.

Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Damola yóò máa sọ ohunkóhun lẹ́yìn tí ìròyìn gbé e pé òun àti ìyàwó rẹ̀, Bukola Awoyemi ti pínyà.

Ẹ ó rántí pé láti bí ẹnu ọjọ́ mélòó kan ló dàbií wí pé nǹkan kò ti lọ déédé nínú ìgbé ayé Damola àti ìyàwó rẹ̀, Arugba.

Ṣaájú ni Arugba ti kéde pé kò sí nǹkankan láàárín òun àti Damola mọ́ lẹ́yìn tí ìròyìn ti ń gbe àwọn méjéèjì ti pínyà.

Arugba ní àwọn kò ṣe ìgbéyàwó, pé ọmọ lásán ni àwọn bí fún ara àwọn àti pé sì ti pínyà báyìí.