Ẹ gbà mí, mílíọ̀nù mẹ́ta ni mo bá nínú akoto ìjọba - Gómìnà tuntun, Dare gbarata

Oríṣun àwòrán, Daudalawal001
Gomina tuntun to ṣẹṣẹ de ori alefa ni ipinlẹ Zamfara Duda Lawan Dare ti ke gbajare lori ipo to ba akoto owo ijọba ni ipinlẹ naa.
O ni lati igba ti wọn ti burawọle sipo fun oun, inu gbese loun wa bayii nitori aisi owo ninu akoto ijọba.
Gomina naa ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC ṣalaye iru ipo ti o ba akoto owo ipinlẹ naa lẹyin toun gba ijọba ni ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Kaarun.
O ni yatọ si miliọnu mẹta Naira tawọn ba ninu akoto owo ijọba ko fẹẹ si owo kankan ninu rẹ.
''Mo ri akanti kan, mo lero pe nkan bii miliọnu mẹta tabi mẹrin Naira pere la ba ninu rẹ''.
O ni lọwọ bayii ibi ti oun yoo ti ri owo ya lati san owo oṣu mẹrin ti ijọba jẹ oṣiṣẹ loun n wa.
Gbogbo nkan lo ti dẹnukọlẹ ni Zamfara
Gomina Dauda ninu ọrọ rẹ ṣalaye idi ti wọn fi n ṣe iwadii Gomina tẹlẹ ri.
O ni nipa nkan to n ṣẹlẹ lọwọ bayii ni Zamfara ko si owo kankan ninu akanti awọn ẹka ijọba ni ipinlẹ naa nitori wọn jẹ wọn laimọye miliọnu Naira.
Bẹẹ lo sọ pe wọn wọn ti dawọ sisan owo fawọn oṣiṣẹ aabo ati pe ẹka eto ẹkọ naa ti dẹnukọlẹ
''Lonii awọn akẹkọọ to fẹ kọ idanwo WAEC ati NECO ko ribi kọ idanwo nitori pe ijọba jẹ awọn ajọ idanwo yi ni owo to le ni biliọnu kan Naira.''

Oríṣun àwòrán, officialdrbellomatawalle
Mo ti bẹrẹ si ni yawo lati san gbese to wa nilẹ
Gomina Dauda sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ ti Gomina to jẹ ṣaaju rẹ Bello Matawalle sọ pe oun fi owo to le ni ogun biliọnu Naira silẹ sinu akoto ijọba.
O ni ''mo fẹ ko fi ibi ti owo yi wa han mi ko si fi ẹri han gbogbo aye pe oun fi ogun biliọnu Naira kalẹ fun wa.Kete ti moba ti ri owo yi ni maa bẹrẹ si ni san gbese owo oṣu mẹrin to jẹ awọn oṣiṣẹ''
O ni kani owo yi wa lootọ, oun yoo ti fi san lara ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ aabo lati mu aabo to peye ba ipinlẹ naa.
''Ni bayii ijọba mi ni lati ya owo lati le koju ipenija aisi omi mimu fawọn araalu Zamfara''
Gomina naa sọ pe o ti le ni oṣu mẹrin bayii ti omi mimu ti wa faraalu ati pe ipenija yi ṣi wa nibẹ amọ ijọba oun ti n gbe igbesẹ lati koju rẹ.
Bẹẹ lo ṣeleri lati san owo oṣu oṣiṣẹ ijọba ki ọdun ileya to de.
O ni bayii, oun wa owo toun yoo ya lati le fi san tabi mu adinku ba iye owo oṣu ti ijọba jẹ awọn oṣiṣẹ.
''Bo ṣe le wu ko ri, mo maa san owo oṣu yi. Bi Ọlọrun ba fun mi ni ipa, mo maa san nitori ẹtọ wọn ni mo si ṣeleri lati ma fi ẹtọ wọn dun wọn''















