Àwọn olóṣèlú alátẹnujẹ kan fẹ́ lo àìlera Akeredolu fi ja ìpínlẹ̀ Ondo lólè – Amúgbálẹ́gbẹ́ fún gómìnà Akeredolu

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, oluwarotimi akeredolu/facebook

Amugbalẹgbẹ agba fun gomina Akeredolu lori ọrọ akanṣe iṣẹ, Ọmọwe Doyin Ọdẹbọwale ti bu ẹnu atẹ lu awọn oloṣelu kan to ni wọn n ṣe ipade bonkẹlẹ kiri lati fi ọbẹ ẹyin jẹ gomina ipinlẹ Ondo lole.

Ọmọwe Ọdẹbọwale ninu atẹjade kan eyi to fi sita ṣalaye pe awọn oloṣelu kan ni ipinlẹ Ondo n lo aisinile ologini gomina Akeredolu lati fi sọ araa wọn di ekute ile to fẹ ti ẹnu bọ aṣuwọn ipinlẹ naa,

O ni ọgbọn ti awọn oloṣelu naa n da ni lati da ina edeaiyede silẹ laarin awọn oṣiṣẹ ijọba kan lọna ati lee fi gba akoso agbara ni ipinlẹ naa.

Rukerudo lagbo oṣelu ipinlẹ Ondo nitori ailera Akeredolu

Ọpọ rukerudo lo ti n waye loju agbami oṣelu ati iṣejọba nipinlẹ Ondo lẹnu lọwọlọwọ yii nitori ipo ailera ti gomina ipinlẹ naa Arakunrin Rotimi Akeredolu wa.

Bakan naa ni iroyin miran tun jade lawọn asiko kan pe awọn oloṣelu kan n gbe gbọyisọyi kiri nipa igbakeji gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Ayedatiwa atawọn ọmọ igbimọ iṣejọba ipinlẹ naa kan pe wọn n gbimọran ati yẹ aga mọ gomina Akeredolu nidi

Amọṣa gomina Akeredolu bomi pa eyi pẹlu bi o ṣe fa akoso ijọba le igbakeji rẹ lọwọ gẹgẹbi adele gomina, to si gba isinmi lọ lati tọju ara rẹ.

Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, facebook/oluwarotimi akeredolu

“Pẹlu gbogbo bi awọn eeyan ipinlẹ yii ṣe n gbadura kikankikan fun alaafia gomina lati pada si ẹnu iṣẹ fun itẹsiwaju ojuse rẹ fun araalu, nṣe lawọn arijẹnidimadaru alatẹnujẹ kan n lepa ati da edeaiyede silẹ nitori atẹnujẹ ara wọn.”

Amugbalẹgbẹ agba fun gomina Akeredolu lori ọrọ akanṣe iṣẹ naa tun yọju rẹ sita pe nṣe lawọn oloṣelu naa n ṣe agbodegba kaakiri fun itankalẹ irọ ati ọrọ kobakungbe tako gomina Akeredolu ati idile rẹ.

Laipẹ yii ni awọn kan gbe iroyin kiri pe o ti jade laye, ki ijọba ipinlẹ Ondo to pa ina gbọyisọyi naa pẹlu awọn aworan atawọn fidio gomina naa.