‘Omijé gba ojú mi kan’, Davido ń dárò ní àyájọ́ ‘Father’s Day’

Oríṣun àwòrán, davido
Bi gbogbo agbaye ṣe n ṣe ajọyọ ayajọ awọn baba, iyẹn ‘Father’s day’, Gbajumọ akọrin takasufe, Davido ti sọ pe iṣoro nla ni ayẹyẹ ayajọ awọn baba ti ọdun yii jẹ fun oun.
Davido sọ eyi ninu awọn atẹjade pelebe-pelebe to fi si oju opo ayelujara instagram rẹ lọjọ Aiku.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni ọdun 2022 ni gbajumọ akọrin ‘ọmọ Baba Olowo’ naa padanu kan lara awọn ọmọ rẹ, Ifeanyi to jẹ ọmọkunrin kan ṣoṣo to ṣi wa laarin oun ati iyawo rẹ Chioma.
Amọṣa Davido ko ṣai dupẹ lọwọ Eleduwa fun okun to fun un lati la ipenija naa ja.

Oríṣun àwòrán, davido

Oríṣun àwòrán, davido

Oríṣun àwòrán, davido
Ninu awọn atẹjade naa, Davido kọ ọ ‘Ayajọ awọn Baba ‘Father’s day’ to nira diẹ fun mi...ṣugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun okun. Awọn ọjọ kan wa ti yoo maa ri bi eyi.”
Bakan naa lo tun ṣalaye pe omije gba oju oun kan ni ni ayajọ awọn Baba tọdun yii.
O wa fi kun pe o da oun loju pe nnkan yoo pada si daadaa fun oun titi lae.








