Kò sí ọba kankan nílẹ̀ Yorùbá tó le fọwọ́ sọ̀yà pé Ifá ló yan òun – Oluwo

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM
Oluwo ti ìlú Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi Adewale ti ní ọ̀rọ̀ ọba jíjẹ nílẹ̀ Yorùbá kò sí lọ́wọ́ Ifa bíkòṣe lọ́wọ́ àwọn gómìnà.
Oba Akanbi ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olódùmarè ti yan orí tí yóò bá dádé láti òde ọ̀run síbẹ̀ ẹni tí gómìnà bá yàn ni Ọlọ́run yàn láti dépò ọba.
Oba Akanbi sọ̀rọ̀ yìí nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú ìwé ìròyìn Nigerian Tribune.
Oba Akanbi fi kun un pé ni iwoye ti oun lọwọ yii, awọn gomina ipinlẹ ti lagbara ju ifa lọ bi a ba n sọrọ ọba jijẹ nilẹ Yoruba.
“Kò sí ọba kankan nílẹ̀ Yorùbá tó lè sọ wí pé Ifa ló yan òun, ẹni tí gómìnà bá ti mú ni yóò di ọba.”
“Kódà nígbà ayé àwọn baba ńlá wa, ẹni to bá ni agbára jùlọ ló máa ń dé ipò ọba.”
'Ipo ọba ti mo wa ko bu kun ọrọ ati ọla mi'
Nígbà tó fèsì sí ìbéèrè bóyá ọrọ̀ ti lékún lẹ́yìn tí ó di ọba, Ọba Abdulrasheed Akanbi ní kókó ohun tí wọ́n torí rẹ̀ yan òun ni láti sin àwọn ènìyàn ìlú òun, Ohun tí òun sì gbájúmọ́ nìyẹn.
Ó ní òun kò lékún nínú ọrọ̀,àmọ́ ènìyàn ìlú òun ni ọrọ̀ òun.
Oba Akanbi fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé òun jẹ́ ọba tó gbọ́ afẹ́ sibẹ gbogbo nǹkan tí ohun ini oun ni òun fi máa ń sin àwọn ènìyàn ìlú òun.
Ọba aláyé náà ni ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn ìlú òun kìí fẹ́ kí èèrà rin òun tó sì jẹ́ wí pé nígbà tí àwọn akn dìde láti yọ òun nípò, àwọn ará ìlú lọ fárígá pé àwọn kò ní gbà.
'Lootọ gomina lo n yan ọba, amọ emi ko mọ gomina ki n to jọba'
Oba Akanbi ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé òun kò mọ gómìnà ìpínlẹ̀ àwọn sójú nígbà tí wọ́n fi máa yan òun gẹ́gẹ́ bí Oluwo, ó ní Olódùmarè ló ṣínà bí òun ṣe máa dépò náà fún òun.
“Nígbà tó ku bí oṣù mélòó kan tí mà á jọba ni ọ̀nà kan ṣí fún mi láti mọ gómìnà.”
“Èmi àti gómìnà kò pàdé rárá títí di ó ku ọ̀la tí wọ́n kéde orúkọ mi gẹ́gẹ́ bí Oluwo ti ìlú Iwo.”
“Iṣẹ́ Olódùmarè nìyẹn, Ọlọ́run àwa Yorùbá, iṣẹ́ rẹ̀ kìí sì í yéni.”
'Àwọn ènìyàn tó máa ń sọ wí pé wàhálà mi pọ̀ kò mọ̀ wí pé ẹ̀tọ́ mi ni mò ń jà fún'
Oluwo tẹ̀síwájú pé ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọ̀pọ̀ ènìyàn máa fi ń wo òun, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ tó máa ń sọ wí pé òun jẹ́ oníwàhálà ẹ̀dá ni kò mọ òun tí òun ń jà fún ní ọ̀pọ̀ ìgbà.
Ó ní gẹ́gẹ́ bí ọba onípò kìíní, àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ máa fi ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀ wọ òun.
Ó ṣàlàyé pé nígbà tí òun fii máa gba ipò Ọba Oluwo, ojú yẹpẹrẹ àti ojú kékeré ni wọ́n fi máa ń wo ipò náà, tí wọn kìí bọ̀wọ̀ fún rárá.
“Mo mọ ipò mi láàárín àwọn Ọba, tí ẹnikẹ́ni kò bá sì fún mi ní ọ̀wọ̀ mi gẹ́gẹ́ bí ipò mi mà á bèrè.”
“Mo máa ń jà fún ẹ̀tọ́ mi ní gbogbo ìgbà kódà kó jẹ́ ní ìlú Abuja.”
“Àwọn tó máa ń sọ wí pé mo ní ìjọ̀gbọ́n kò mọ̀ nǹkan tí mò ń jà fún, mó máa ń jà fún ẹ̀tọ́ mi lọ́nà tó tọ̀nà.”















