Ọlọ́kadà tó fi ipá bá aláboyún oṣù mẹ́jọ lòpọ̀ dèrò àtìmọ́lé

Handcuffs

Oríṣun àwòrán, CGTN Africa

Ọlọkada ẹni ogoji ọdun kan, Akpo Igwe ti dero agọ ọlọpaa ipinlẹ Benue lori ẹsun pe o fi ipa ba alaboyun oṣu mẹjọ lopọ.

Mọlẹbi alaboyun ọhun sọ fun awọn akọroyin pe ṣe ni obinrin naa n bọ lati ọja, to si pe ọkada Igwe pe ko gbe oun dele.

Amọ asiko ti irinajo naa n lọwọ ni afurasi ya bara sinu igbo, to si ṣi aṣọ alaboyun naa wo pẹlu ipa.

Mọlẹbi naa ni “Nnkan bii aago meje alẹ Ọjọru ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti obinrin naa n bọ lati ọja.”

“O pe ọkada, wọn si dunadura pe ki ọkada naa gbe lọ sile.”

“Asiko ti wọn n lọ sile ni ọlọkada ọhun ya sinu igbo to si fi ipa ba laṣepọ.”

“Ibi to ti n fipa ba a lopọ lọwọ ni obinrin naa ti daku, to si ro pe o ti jẹ Ọlọrun nipe, o wọ ara rẹ jade ninu igbo, o si lọ ju si ẹgbẹ odo kan.”

Mọlẹbi naa ṣalaye siwaju si pe aarọ ọjọ keji ni obinrin ọhun to taji.

O fi kun pe awọn mọlẹbi rẹ ti n wa loru ọjọ naa titi di ọjọ keji ki wọn to ṣawari rẹ leti odo ti afurasi ọhun ju u si.

O sọ siwaju si pe “Nigba ti a ri, a gbe digbadigba lọ sile iwosan, a si fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.”

“Oyun oṣu mẹjọ lo wa ninu obinrin naa, yoo si bimọ laipẹ.”

Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, SP Catherine Anene ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ati pe iwadii ti n lọ lọwọ.

Anene ni wọn ti gbe ẹjọ naa lọ si oriko ileeṣẹ ọlọpaa Benue, eyi to wa ni ilu Makurdi fun iwadii to peye ati pe afurasi naa ti wa ni ahamọ nibẹ.