Dibu Ojerinde, ọmọ mẹ́ta àti ìyàwó ọmọ rẹ̀ ń jẹ́jọ́ ẹ̀sùn títa ilé rẹ̀ tíjọba gbẹ́sẹ̀ lé ní Ghana torí ìwà àjẹbánu

Aworan

Oríṣun àwòrán, JAMB

Adari ajọ Jamb tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Adedibu Ojẹrinde ti n jẹjọ ẹsun mii to nii se pẹlu tita ọhun ini ijọba to wa lorilẹede Ghana.

Bakan naa ni wọn fi ẹsun yii kan awọn ọmọ rẹ ọkunrin mẹta, to fi mọ iyawo ọmọ rẹ pẹlu.

Ni iwaju adajọ ileẹjọ giga to kalẹ si ilu Abuja ni igbẹjọ naa ti n waye.

Ẹsun ti wọn fi kan Ojerinde atawọn ẹbi rẹ yii ni pe wọn ta ile ijọba to wa ni agbegbe ojule 4, Ahomko Drive, Achimota Phase Two, Accra, Ghana.

Gbogbo awọn ti wọn fi ẹsun kan naa si peju si ileẹjọ lati sọ tẹnu wọn.

Ile naa ni wọn ni Ọjẹrinde ati awọn mọlẹbi rẹ ta lẹyin ti ijọba gbegile nitori ẹsun iwa ajẹbanu.

Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan an pe o lo ayederu orukọ lati fi ra ileeṣẹ, to si tun lo apo iṣuna ti kii ṣe tirẹ lati fi ṣi ileepo.

Iwe ẹsun naa tun fikun un pe awọn ọmọ rẹ tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi onigbọwọ fun awọn to ra ile naa.

Amọ nigba ti wọn ka iwe ẹsun naa ti wọn fi ẹsun kan wọn seti gbogbo wọn, wọn ni awọn ko jẹbi ẹsun naa.

Adajọ to n gbọ ẹsun naa, Inyang Ekwo wa gba ẹjọ awọn ti wọn fi ẹsun kan naa, to si ba beeli awọn ọmọ ati iyawo-ọmọ rẹ pẹlu oniduro ni ogun miliọnu naira.

Amọ Ojẹrinde ni adajọ ko gba beeli rẹ nitori pe o n jẹjọ iwa ajẹbanu miran ni ileẹjọ giga ni ilu Minna ati omiran ni iwaju ileẹjọ giga ni Abuja.

Bakan naa ni adajọ kọ lati jẹ ki awọn afurasi naa jade kuro lorilẹede Naijiria titi igbẹjọ naa yoo fi pari, ti wọn si gba iwe irinna si ilẹ okeere wọn.

Igba kinni kọ niyii ti wọn ti fi iwa ajẹbanu kan Ọjọgbọn naa lasiko to wa ni ipo adari ajọ Jamb ni Naijiria.