Kò sí nínú gbogbo àwọn ọmọ tí mò ń kọ́ ní bọ́ọ̀lù tó rí mi bíi àkàndá – Olùkọ́ni agbábọ́ọ̀

Àkọlé fídíò, Kò sí nínú gbogbo àwọn ọmọ tí mò ń kọ́ ní bọ́ọ̀lù tó rí mi bíi àkàndá – Olùkọ́ni agbábọ́ọ̀

Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe o loju iṣẹ ti ẹni to ni ipenija oju le ṣe, ati pe lara awọn iṣẹ ti akanda ẹda ko le ṣe ni bọọlu gbigaba.

Amọ ọrọ ko ri bẹẹ fun ọkunrin kan ẹni to ni ipenija oju, Babatunde Kareem, to jẹ olukọ ere bọọlu niluu Akure.

Kareem, to jẹ olukọ ẹgbẹ agbabọọlu 'Glorious Footabll Academy' ni nnkan bii ọdun marundinlọgbọn sẹyin ni ipenija oju naa bẹrẹ.

"Bi mo ṣe di akọnimọọgba bọọlu gẹgẹ bii afọju"

Gẹgẹ bii ohun to sọ, lati kekere lo ti fẹran bọọlu alafẹsẹgba, o si ti gba bọọlu daadaa ri, ki ipenija oju naa to de.

O ni oun gbagbọ pe oun yoo ṣe oriire nidi bọọlu gbigba, amọ nigba ti ipenija oju waye, loun ya si idi iṣẹ akọnimọọgba.

Kareem ni "ki n to ni ipenija oju, emi naa ti gba bọọlu ri, mo ti gba bọọlu lọpọlọpọ igba."

"Mo mọ aayo to wa ninu rẹ, ti mo si ri pe ibi ti mo le gba lati ṣe oriire ninu rẹ ni eleyii."

"Ṣugbọn nigba ti ipenija naa de, ni mo ṣe wa wo pe ko si ibi ti a tun le gbe gba mọ ju pe ki n gbajumọ bọọlu ti mo fẹran lọpọlọpọ yii."

"Idi niyen ti mo fi mu ni aayo mi, lati jẹ olukọni agbabọọlu."

Kareem ti gba oniruru ami ẹyẹ labẹle gẹgẹ bii olukọni agbabọọlu.

Wo fidio to wa loke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti Kareem sọ.