Abdulfatai Balogun: N kò ríran àmọ́ oníṣòwò Yoghurt aládàńlá ní mí tó ń fi àwìn sàánú fún oníbàárà

Àkọlé fídíò, Abdulfatai Balogun: N kò ríran àmọ́ oníṣòwò Yoghurt ní mí tó ń fi àwìn sàánú fún oníbàárà

Kayeefi nla ni iroyin yii nitori o sọwọn pupọ lati ri ẹni ti ko riran, to n tun ẹrọ to n sọ omi di yinyin alada nla se ati ẹrọ amomitutu.

Nilu Ilorin, gbajumọ bii isana ẹlẹẹta ni Abdulfatai Balogun, ẹni to n ta oniruuru yoghurt fawọn eeyan to n tun sa, eyi to jẹ alada nla.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori bo se rọrun fun lati maa tun ẹrọ se, to si tun n ta Yoghurt lai riran, Balogun ni aanu Ọlọrun ni oun ri gba.

Bawo ni aisan oju didun naa se bẹrẹ:

Balogun ni akọsẹmọsẹ mẹkaniki ni oun nilu Eko, ki ipenija oju naa to bẹrẹ lọdun 1995.

O salaye pe oun tiraka lati tọju rẹ amọ gbogbo aayan oun lo ja si pabo.

Onisowo Yoghurt naa ni awọn eeyan n sọ fun oun pe ọrọ ipenija oju naa ni ọwọ aye ninu ni ko jẹ ki oun tete wa itọju fun.

Amọ eyi lo ni o mu ki ọrọ naa yiwọ patapata.

Aago marun ni mo maa n ji lọ si sọọbu lati to Yoghurt mi:

Abdulfatai Balogun ni oun ni gbajugbaja to tobi julọ nidi okoowo ohun mimu aladun Yoghurt lorisirisi nilu Ilorin.

O ni aago marun owurọ ni oun maa n ji lọ si sọọbu oun lati yanju awọn eroja ohun mimu naa to ti di, ki awọn onibara to de lati ra wọn.

O wa salaye pe sọọbu meji ni oun ni amọ oun ko tii ni agbara lati ra ẹrọ amunawa nla ti yoo gbe ọpọ ẹrọ firisa ti oun n lo.

Balogun wa n dupẹ lọwọ Ọlọrun pe oun n ri taje se nidi okoowo naa, ti oun si ti kọ ile funra oun, bakan naa ni oun ti ran ọmọ jade nile ẹkọ giga.

Mo maa n ta Yoghurt awin fawọn onibara ti ko lowo lọwọ lati saanu fun wọn:

Bakan naa ni ọkunrin to ni ipenija oju naa kede pe ipo ti oun wa ko se idiwọ fun oun lati se aanu fun awọn eeyan to nilo iranlọwọ.

Abdulfatai Balogun ọpọ onibara ni ko lowo lọwọ lati ọja lọwọ oun, ti oun kii si wo ipo ti oun wa, ki oun to se wọn laanu.

O ni oun maa n ta ọpọ eroja ohun mimu Yoghurt fun wọn ni awin, igba ti wọn ba si ta tan, ni wọn yoo to mu owo wa.

O wa gba awọn eeyan ti ko ri ọwọ họ̀=ri niyanju, paapaa awọn eeyan to ni ipenija ara, lati mase duro de igba ti owo nla ba de ọwọ wọn, ki wọn to bẹrẹ okoowo.

O ni ẹrọ to n sọ omi di yinyin ẹyọ kan soso ni oun fi bẹrẹ okoowo naa, ko to di pupọ mọ oun lọwọ.