Blind Oniru: Muinat Abdulfatai ní òun ro ara òun pin àmọ́ irú títà fún òun ní ìrètí ọ̀tun

Àkọlé fídíò, Blind Oniru: Muinat Abdulfatai ní òun ro ara òun pin àmọ́ irú títà fún òun ní ìrètí ọ̀tun

Agbara wa ninu ipenija ara, ohun to ba si wu nii se, bii idan lo n ri.

Muinat Abdulfatai ni ipenija oju lati kekere, ti ko si riran rara amọ okoowo iru to nira fun abarapa lati se gan lo dawọle.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to gbe de idi okoowo naa, Muinat salaye pe isoro ti oun koju nile ọkọ lo sun oun de ilw baba oun, ti oun si fi dawọle okoowo iru.

O ni ile ẹkọ ni oun wa ti wahala oju naa fi bẹrẹ, ti ọkọ oun fi fẹ oun amọ ko tọju oun rara, ti ẹrọ ata ti oun fi n se isẹ aje si bajẹ.

Idi ree to fi ni oun fi gbe majele jẹ lati tọrọ iku nigba ti ireti pin amọ Ọlọrun ko fun oun, ti ile iwosan si gba oun silẹ.

O ni idi isẹ iru tita ni oun pada si, ti oun si n fi bọ ara oun atawọn ọmọ pẹlu.

Nigba to n salaye awọn ipenija to wa nidi iru sise, Muinat ni oun ko le se agbe jẹun nitori oun naa fẹ gbe nnkan rere se nile aye, idi ree ti oun fi dawọle okoowo kan.

O ni oun ni eeyan kan to maa n ba oun sa okuta kuro laarin awọn iyere amọ oun gan maa n sa funra oun nipa mimu iyere ni ẹyọ kọọka.

Obinrin to ni ipenija naa ni atẹlẹwọ ẹni ni kii tan ni jẹ, oun ko si fẹ fi iya jẹ ara oun, ni oun ko fi tọrọ bara.