'Aláàbọ̀ ara tó ń dari ọkọ̀ ojú pópó ní àìlera kìí ṣàrùn'
Usman gba àwọn awakọ̀ níyànjú ki wọ́n máa rọra sáré lójú pópó.
O sọ itan aye rẹ àti bi oun ṣe pinnu pe oun ko ni jẹ ki aabọ ara oun sọ oun di ẹni ti yoo maa tọrọ kiri.
O mẹnuba ifẹ Naijiria ti oun fi n sin ilẹ baba oun nipa didari ọkọ loju titi.
Shehu sọrọ lori oriṣii awọn awakọ to wa loju popo ni Naijiria bii atawọn ero to n ronu rinlọ loju titi.
O ni o ṣe pataki ki awakọ maa ni suuru to ba fẹ de orita.
O gba awọn awakọ nimoran lati máa ṣọra ṣe loju popo.
O gba awọn akanda ẹda atawọn alaabọ ara miran niyanju pe, ipenija kò yẹ kò sọni di alagbe ati ole.
