Ikú àgùnbánirọ̀: 'Irọ́ ni pé a fi itọ́jú Linda Igwetu fa'lẹ̀'

Oríṣun àwòrán, Igwetu Linda Nkechi/Facebook
Ọrọ ń bá ọ̀rọ̀ bọ̀ lórí ikú àgùnbánirọ̀ Linda.
Lórí awuyewuye to waye lori iku Linda Igwetu, agunbanirọ kan ti ọlọpàá kan torukọ rẹ n jé Benjamin Peters yinbọn pa ni Abuja ni Ọjọru, awọn alaṣẹ Ile Iwosan Garki nibi to ku si ni irọ ni ahesọ pe awọn ko tete fun un ni itọju.
Ile iwosan naa to gbe atẹjade kan sita ninu eyi ti wọn ti ṣalaye oun to ṣẹlẹ ki Linda to gbẹmi mi, so pe oloogbe naa ko padanu ẹjẹ nitori pe awọn n beere iwe lati ọdọ ọlọpaa ki wọn to le tọju rẹ.
Atẹjade naa ti adari ile iwosan naa, Dokita Nyomudim Essen, bu ọwọ lu, sọ pe aago mẹta kọja iṣẹju marun un ni wọn gbe Linda digbadigba de ọdọ wọn ti awọn dokita si ja fitafita lati doola ẹmi rẹ.

Oríṣun àwòrán, Garki Hospital
Ile Iwosan naa ni, "A fa ẹjẹ si oloogbe naa lara, a dẹ tun ṣe iṣẹ abẹ ranpẹ fun un bo tilẹ jẹ pe a ko tii gba owo kankan lasiko naa.
Ṣugbọn o ṣe ni laanu pe pabo ni gbogbo ipa wa ja si. Irọ ni iroyin pe a fi itọju rẹ falẹ."
Olori ile aṣofin agba, Bukọla Saraki ba Chinenye to jẹ ẹgbọn oloogbe naa sọrọ lori foonu lanaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Saraki tun so pe ile igbimọ naa yoo ṣe iwadii lori iku naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ọgbẹni Segun Awosanya to jẹ ajafẹtọ ọmọniyan to wa nidi ipe fun atunto SARS lori ẹsun pipa awọn ara ilu bi ẹran so pe oun ti kọ iwe ifẹhonuhan si Ile Igbimọ Aṣofin Agba ati Minisita fun ọrọ abẹle Abdulrahman Dambazau.
Awosanya gbe iwe naa de iwaju Minista fun Idajọ ti o tun jẹ amofin patapata fun orilẹ-ede Naijiria.













