World Cup 2018: Ṣé àwọn tó kù ní Moscow ló tó gbangba sùn?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ́ Abamẹta nidije ipò kẹta ti waye nigba ti ife ẹyẹ yóò doríkọ orilẹ-ede tó fẹ́ loni.
Ipele kò-mẹsẹ̀-o-yọ nìdíje dé, O ku orilẹ-ede meji pere ni Russia, iyẹn France ati Croatia nigba ti Belgium ti gba ipo kẹta lẹyin ti wọn ṣíná fún England.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn orilẹ-ede ilẹ Adulawọ maraarun ni wọn ti já ti onikaluku ti pada sile. Awọn naa ni: Naijiria, Egypt, Morocco, Tunisa ati Senegal.
Saudi Arabia, Iran, Australia, Iceland, Peru, Costa Rica, Serbia, South Korea, Panama, ati Poland pẹlu awọn miran naa ti ja ninu idije.
Nigba ti àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ bii Germany to gba ife ẹyẹ gbẹyin paapaa ti kuro ni Russia pada sile.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipele kò-mẹsẹ̀-o-yọ nidije déé duro bayii ni Russia ti ẹnikẹni to ba ti fidi rẹmi n pada sile.


Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn wo ló ti lọ sílé?
Awọn ikọ agbabọọlu orilẹ-ede bii Argentina, Portugal, Spain, Denmark, Mexico, Japan. Switzerland ati Colombia ti ko ẹrù wọn pada sile.
Awọn to ku ti won n kopa ninu ipele ṣikeji si àṣekagba ni: Uruguay, France, Brazil, Belgium, Sweden, England, Russia ati Croatia.
Ipele kò-mẹsẹ̀-o-yọ, idije to ṣikeji si aṣekagba lo déé duro bayii ni Russia ti ẹnikẹni to ba ti fidi rẹmi n pada sile.
Àwọn wo ló ti lọ sílé lẹ́yin ipele ṣikejì?
Orilẹ-ede Uruguay, ati Brazil ti yọ kuro ninu ipele yii nigba ti France ati Belgium ṣíná fún wọn.
Bakan naa ni Sweden ati Russia to n gbalejo idije todun 2018 naa ti ja kuro ninu idije.
Ipele kò-mẹsẹ̀-o-yọ, esi idije to kangun si aṣekagba ni Russia ti awọn to ti fidi rẹmi ti pada sile.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àṣekágbá World Cup 2018
Orilẹ-ede England pada lọ sile lai duro gba ife ẹyẹ ti wọn fẹ gbe lọ sile nigba ti Belgium gbo ewuro si oju wọn pelu ami ayo meji sodo lọjọ Abamẹta.

Oríṣun àwòrán, @fifa
Oni ni France yoo koju Croatia lati mọ orilẹ-ede ti ife ẹyẹ agbaye n lọ fódun 2018.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

















