Ọlọ́pàá yìnbọn pa àgùnbánirọ̀ nígbà tó ku ọjọ́ méjì kó gbàwé ẹ̀rí

Oríṣun àwòrán, Igwetu Linda Nkechi/Facebook
Òní ló yẹ ki Linda gba ìwé ẹ̀rí pé o parí àgùnbánirọ̀ rẹ.
Ọwurọ̀ Ọjọ́rú ni Linda Igwetu to jẹ agunbanirọ ti ọlọpaa pa ati awọn akẹgbẹ rẹ jade lọ ṣe àjọyọ pipari ìsìnrú'lú ọdun kan wọn.
Ẹgbọn oloogbe naa, Chinenye ṣalaye fun BBC bi ọrọ naa ṣe jẹ, o si fẹsun kan ọlọpàá pe wọn parọ lori ọrọ naa.
O ni bii agogo mọkanla alẹ ni Linda pari iṣẹ ni Outsource Global Company Mabushi to n ba ṣiṣẹ ni ọjọ Iṣẹgun.
Lẹyin naa ni oun ati awọn alajọṣiṣẹ rẹ lọ sile igbafẹ kan lati lọ ṣe ajọyọ ipari ìsìnrú'lú eyi ti ayeye rẹ yẹ ko waye loni (Ọjọ́bọ̀) jakejade orilẹede Naijiria.
Chinenye ni, "Ọlọpaa ni wọn gbọ ti aburo mi n paruwo 'ẹ gba mi, wọn ti ji mi gbe' ni awọn ṣe yinbọn si ọkọ naa. Ṣugbọn irọ ni wọn pa. Awọn alabaṣiṣẹ aburo mi ni awọn mejeeji to wa ninu ọkọ pẹlu rẹ. Mo tilẹ mọ ọkan lara wọn.
"Ọlọpaa ti ti awọn mejeeji mọ le bayii. Ọkan lara wọn sọ fun mi wipe, awọn ko tilẹ ri ibudo ọkọ ọlọpaa (checkpoint). Wọn ni iro ibọn nikan lawọn gbọ bi awọn ṣe n kọja ti Linda si paruwo pe ibọn ti ba oun o.
"Ṣe to ba jẹ tootọ ni pe wọn ji aburo mi gbe, ṣe nkan to kan ni pe ki wọn yinbọn pa?"
Ẹgbọn oloogbe naa, Chinenye, ke gbajare lori Twitter pe oun fẹ idajọ to tọ lori iku aburo oun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2
Ọlọpaa to yinbọn wọ atimọlẹ
Ọgbẹni Segun Awosanya to jẹ ajafẹtọ ọmọniyan to de ile iwosan naa laipẹ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni nkan bii agogo mẹta oru ni wọn kuro nibi ajọyọ wọn lati dari sile. Ṣugbọn bi wọn ṣe kọja Cedi Plaza ni Abuja ni wọn pade awọn ọlọpaa. Ọkan lara wọn ti oruko rẹ n jẹ Benjamin Peters doju ibọn kọ ọ ninu ọkọ ti wọn wa.
Ẹgbẹ ikùn ni a gbọ pè ibọn ti ba Linda, ti wọn si gbe e digbadigba lọ ile iwosan. Ajafẹto Awosanya ni Linda ti padanu ẹjẹ de bi pe, wọn ko le doola ẹmi rẹ.Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa FCT Abuja, Anjuguri Manzah, sọ pe iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa. Ṣugbọn ko sọ ohun ti wọn ti ṣe fun ọlọpàá to yinbon naa.
Ileeṣe BBC wadii lẹnu awọn to n ṣiṣẹ lori ọrọ naa, wọn si sọ pe, ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe Peters si atimọle bayii.
Awosanya ni Ile Igbimọ Aṣofin Agba ati minisita fun ọrọ abẹle Abdulrahman Dambazau ti gbọ si ọrọ naa. O tun sọ pe ajọ ajafẹtọ oun ti kọ iwe ẹhonu bayii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ọrọ naa ti di yanpanyanrin
Ọrọ naa ti n fa ikanra fun awọn ọmọ Naijria lati igba ti iroyin ti kan nipa iku Linda, latari pe bi oṣu meloo kan sẹyin ni wọn ti n ke gbajare nipa iwakiwa awọn ọlọpaa ni Nigeria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4

End of X post, 5
Awọn kan tilẹ n sọ pe, boya ile iwosan ijọba ti Garki ti wọn gbe oloogbe naa lọ si ni ko ṣe iṣẹ wọn to, sugbọn ọgbẹni Awosanya ni ko ri bẹẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6