Bukola Saraki: Ẹ̀mí gbogbo ọmọ Nàíjíríà ló se pàtàkì

Oríṣun àwòrán, Nigeria Senate
Ile Igbimọ Asofin Agba ni orilẹede Naijiria ti pinnu lati se iwadi kikun lori iku to pa arabinrin agunbanirọ, Linda Angele Igwedu ti awọn eniyan sọ wi pe awọn ọlọpa yin ibọn pa.
Sẹnatọ Atai Aidoko to gbe ọrọ naa kalẹ ni iwaju ile sọ wi pe arabinrin naa n lọ ile pẹlu awọn ọrẹ rẹ nigbati wọn yin ibọn lu u ni ilu Abuja, ti awọn ile iwosan si kọ lati tọju rẹ nitori ko si iwe lati ọdọ awọn ọlọpaa.
Aarẹ Ile Asofin, Bukola Saraki ninu ọrọ rẹ sọ wi pe "ẹmi ẹni kọọkan lo se pataki, paapaa awọn ọdọ ti wọn sẹẹsẹ n bẹrẹ igbe aye wọn.
Lẹyin naa ni ile igbimọ wa pasẹ fun igbimọ ile to n risi ọrọ ọdọ ati ere idaraya lati se iwadi kikun lori iku agunbanirọ naa, ki igbimo ile to n risi ọrọ̀ọ ilera lati se iwadi lori idi ti ile iwosan se kọ lati fun u ni itọju.









