Samuel Ajirebi: Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ Òṣèré ló sọ pé àwọn wọ iṣẹ́ tíátà torí fíìmù ìgbà kékeré mi tí wọ́n wò

Àkọlé fídíò, Samuel Ajirebi ọmọ ọdún mẹ́rin àtijọ́ rèé, ó bojú wo fíìmù rẹ̀ ní kékére, máàkì tó fún ara rẹ̀ rèé

"Bi mo ba wo awọn iṣẹ fiimu ti mo ṣe nigba yẹn, o maa n jẹ iwuri fun mi, nigba mii mo si maa n bu ara mi pe loju ara rẹ ṣe iṣẹ tiata naa lo ẹ nibi".

Ọmọ gbajumọ ati agba oṣere fiimu Yoruba, Kayode Olasehinde ti ẹ mọ si Pa Ajirebi ni Samuel Olasehinde jẹ ti ọpọ si ti mọ si Samuel Ajirebi lati kekere to ti n ba wọn ṣe ere tiata.

Samuel Ajirebi

Oríṣun àwòrán, YouTube/Korede Films

Ẹlomii le ma daa mọ mọ bayii amọ ṣaṣa lẹni ti ko mọ Samuel Ajirebi nigba to wa ni bii ọmọ ọdun mẹrin to maa n ṣe ere. Igba mii, baba rẹ gaan ni yoo tako ninu ere, igba mii ọmọ ẹlomiran ni yoo ṣe ti gbogbo eeyan si maa n kan sara si iṣẹ to n ṣe.

Pa Ajirebi

Oríṣun àwòrán, Korede Films

Ẹwẹ, Samuel funra rẹ boju wo iru awọn ere to maa n ṣe ni kekere o si ni ibi to ti kan sara si ara rẹ bakan naa lo ni ibi to ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹ ara rẹ.

Amọ ta lo lee da Samuel lẹbi ni kekere, leyii to jẹ pe ohun to tilẹ lee ṣe lo n ṣe to si tun n ya awọn eeyan lori.

Samuel Ajirebi

Oríṣun àwòrán, Kerede Films

O ṣalaye awọn nkan to ran an lọwọ lati maa tayọ lasiko to n ṣe ere tiata to jẹ ki oye rẹ tete ṣi si awọn ọrọ ijinlẹ ati owe Yoruba.

Samuel Ajirebi ba BBC Yoruba sọrọ lori bi ọla iṣẹ ti baba rẹ n ṣe ṣe sọ oun naa di ilumọọka lati kekere ninu agbo oṣere.

Samuel ati baba rẹ Ajirebi