Fire guts Apongbon bridge market: Bí iná ń jó ní ọ̀jà abẹ́ afárá Apongbon l'Eko

Ori Afara Apongbon

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe ina nla kan ti burẹkẹ to si ti ba awọn ọja ọpọlọpọ miliọnu Naira jẹ.

Gẹgẹ bi iroyin ti a ko jọ lati ibẹ, ina naa ti da sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ ti awọn ọkọ ko si ribi gba kọja bẹẹ si ni o ti di katakara lọwọ ni agbegbe naa to wa ni Lagos Island ni Eko.

Bo tilẹ jẹ pe ko tii si aridaju ohun to ṣokunfa ina, awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni o bẹrẹ ni nkan bii ago meji oru Ọjọrun ti ko si tii rọlẹ patapata.

Àkọlé fídíò, Samuel Ajirebi ọmọ ọdún mẹ́rin àtijọ́ rèé, ó bojú wo fíìmù rẹ̀ ní kékére, máàkì tó fún ara rẹ̀ rèé

Awọn eeyan ti n fi si ori ayelujara pe ki ẹnikẹni to ba n lọ si ọna CMS wa ọna miran gba tori nibayii ko si ọna miran ti wọn le gba lori Eko Bridge.

Awọn to n gbe ni agbegbe naa sọ fun awọn oniroyin pe ina ọhun ti tan ka de awọn apa ibomiran ninu ọja naa pẹlu aduru akitiyan ti awọn oṣiṣẹ pana pana n ṣe lati le pa ina ọhun.

Ẹwẹ, Oludari ileeṣẹ pana pana, Margaret Adeseye jẹ ko di mimọ pe awọn ti n ṣa gbogbo ipa awọn ati pe laipẹ, wọn yoo pa ina ọhun.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin bo ba ṣe n lọ.

Àkọlé fídíò, Ẹ má fún mi l'ówó bárà, mò ń bọ́ ẹnu púpọ̀, aya àtọmọ mẹ́ta - Oladapo Okalawon Shonde