Buhari's visit to Lagos: Wo ẹnu ibodè ìrìnà òfurufú tí Ààrẹ Buhari ń bọ̀ wá ṣèfilọ́ọ́lẹ̀ ní Eko lónìí

Aarẹ Muhammadu Buhari ti balẹ bagẹ si ipinlẹ Eko fun awọn akanṣe iṣẹ.
Ikini ni ifilọlẹ ẹnu ibode irina ofurufu tuntun ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed ni Eko.

Bakan naa ni Aarẹ yoo tun ṣe ayẹwo irinṣẹ nla fun ajilẹ eyi ti ileeṣẹ Dangote ṣe agbekalẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Presidency
Lafikun, iroyin sọ pe Aarẹ buhari yoo yọju si ibi iṣẹ to n lọ lọwọ ni ibudokọ oju omi kan ni agbegbe Lekki nipinlẹ Eko.

Oríṣun àwòrán, Presidency
'Ọjọ́ méjì àti wákàtí díẹ̀ péré la fún Ramon Adedoyin láti gbé ìwée 'a kò ní ẹjọ́ jẹ́' wá sílé ẹjọ́'
Bi wọn ba pari iṣẹ yii, ohun ni yoo jẹ ibudo oju omi okun to jin ju ni Naijiria bakan naa wọn n woye pe ohun ni yoo jẹ ibudo oju omi to jẹ ti igbalode ju lọ ni Iwọ Oorun Afirika.

Igba ti Aarẹ Buhari ṣe ibwo si ipinlẹ Eko gbẹyin ni ọjọ Kẹsan oṣu Kejila ọdun 2021 nigba to ṣe ifilọlẹ awọn iṣẹ akanṣe kan ni ileeṣẹ ogun oju omi ni Naijiria.
Nibayii, alakalẹ ti wa fun awon oju ona popo mii ti awon eeyan le gba lati yago fun sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ.

















