Oluwo's new bride Firdauz: Lẹ́yìn tí olorì tuntun wọ ààfin rẹ̀, wo bi Oluwo ṣé sòkò ọ̀rọ̀ sì Olori Chanel tó fẹ̀ tẹlẹ

Aworan Oluwo ilu Iwo

"Emi ni ọkọ iyawo tuntun".

Gbolohun yi ni Oluwo ti Ilu Iwo Ọba Abdulrasheed Akanbi fọ lesi fi ṣapẹjuwe ipo rẹ tuntun lẹyin to ṣe igbeyawo pẹlu Olori Firdauz.

Lọjọ Abamẹta to kọja yi ni Oluwo fẹ Firdauz to jẹ ọmọ ẹgbọn Emir Ilu Kano lọwọlọwọ, Alhaji Aminu Ado Bayero.

Ninu ọrọ Oluwo niṣe la ri apẹrẹ pe inu oriade yi dun pẹlu bo se ti ṣe gbe iyawo tuntun saafin lẹyin ọdun diẹ ti ọrọ ko wọ mọ pẹlu Olori tẹlẹ, Channel.

Oluwo ṣapejuwe igbeyawo yi gẹgẹ bi nkan oriire.

O ni ''oriire leeyan maa fi n dahun si awọn inunibini, awọn eleebu.Ti o ba ti n ṣe oriire, iwọ maa wo wọn''.

Oni ni inu mi dun julọ lati ijọ ti mo ti jọba

Oluwo kun fun ayọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe yi pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC debi pe o ni inu oun ko dun lọjọ mii bi ti ọjọ igbeyawo toun ṣẹṣẹ ṣe tan yi.

Oba Rasheed ni inu oun dun pe iyawo alalubarika iyawo Naijiria ni iyawo toun fẹ yi jẹ.

O wa fẹnu tẹnbẹlu iyawo rẹ ti tẹlẹ to ṣe ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi iyawo ti oun ko fẹ niṣu lọka.

Oluwo ati iyawo rẹ tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

''Iyawo ti mo fẹ tẹlẹ, a o san owo ori wọn. A kan mu wọn ni titi ni. Ṣugbọn eleyi, a fi owo fẹ ẹ ni''.

Koda Oluwo ni ki wọn to jẹ ki oun si oju iyawo oun wo, oun san owo.

''Gbogbo nkan la ṣe, a si dupẹ lọdọ Ọlọrun wipe iyawo to da...''

Alujanaa ni itumọ orukọ iyawo mi tuntun

Nigba to n ṣe apejuwe iyawo rẹ tuntun ati itunmọ orukọ rẹ, Oluwo ni iyawo oloriire ni arabinrin ti oun ṣẹṣẹ fẹ yi jẹ.

O ni iyawo alayọ ni ati pe awọn eeyan nlanla ni wọn mu iyawo yi wa lati oke ọya si ilu Iwo.

Oluwo ati Iyawo tuntun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ni idahun si ibeere wi pe ki lo de ti Oluwo ṣe fo lọ si Oke Oya lati lọ fẹ iyawo o fesi pada bayi:

''Ṣe ifẹ mọ eebo? Ifẹ kọja gbogbo nkan. Ko si ofin to de ifẹ. Bo ba wu mi maa fẹ Chinese. Ifẹ ko mọ Ijaw, ko mọ Hausa ko mọ Igbo.''

''Ẹni ti mo nifẹ ni mo fẹ, kii se pe mo fẹ fẹ iran. Ifẹ lo bori gbogbo nkan.''

Àkọlé fídíò, Wòlíì ni ọmọ táà bá bí ni ago kan géérégé ni...Bàbá tó bí Ooni Adeyeye Ogunwusi sọ àṣírí àkọsẹ̀jayé rẹ̀