Oluwo: Telu 1 ní apani ní Olorì òun àná, àmọ́ obìnrin náà ní oríadé ń ṣìṣe ọmọdé

Oluwo ti Iwo ati Chanel Chin

Oríṣun àwòrán, Instagram/Chanel Chin

O ti le ni ọdun meji ti Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu kinni ati aya rẹ, olori Chanel Chin ti juwọ si ara wọn pe o digba.

Amọ ni bii ọsẹ kan sẹyin ni eruku ija miran tun sọ laarin ara wọn, ti oriade naa ati Olori rẹ ana si n ta sira wọn pẹlu ẹfẹ to buru lori ayelujara.

Oba AbdulRasheed lo kọkọ bẹrẹ si ni sọ oko ọrọ si Chanel lasiko ti Oluwo fi atẹjade sita nibi to ti pe Channel ni ọta rẹ, to sun si ibusun kan naa pẹlu oun, to si bi ọmọ fun oun.

Ninu atẹjade ti Oluwo fi lede lo ti sọ wi pe ọta oun pofo, inu oun si dun pupo.

''Oju ọba to bori awọn ọta ree, pẹlu awọn ọta eleyii to n sun pẹlu mi lori ibusun kan naa, to bimọ fun ni, to fun ni ni majele jẹ, to tun gba omo ẹmi lọwọ awọn ọta mi lati pami.''

Oluwo ti Iwo

Oríṣun àwòrán, emperortelu1/Instagram

''Ọna ẹburu lo gba di aya mi, to si n beere owo ituka lẹyin ti imọ rẹ ko ṣẹ, eleyii ti mi o fun un rara.''

''Agbara ti mo ni ti awọn ọta mi ko mọ ni agbara Olodumare, awọn eniyan dide si mi gẹgẹ bi ọta mi, lati gbẹmi mi amọ Olodumare gbe ija mi ja, o si doju ti awọn ọta mi.''

Oluwo ti ilu Iwo naa ni ọwọ ọta kankan ko le e ran oun nitori agbara Olodumare wa sibẹ fun oun, to si n tọ oun sọna ni gbogbo igba.

Àkọlé fídíò, Oluwo Divorce: ko si ẹni ti kò mọ pé ọmọ ilẹ̀ òkèrè ni mó fi ṣe aya

wo ọba alaye ni ilẹ Yoruba to n ṣiṣe ọmọde - Chanel Chin

Lẹyin ti Oluwo fi oko ọrọ ranṣẹ si Chanel Chin lori ayelujara, ni oun naa da pada fun Oluwo, to si bẹrẹ si ṣe afiwe ọba naa pẹlu awọn nkan ke kee ke to pa ni lẹrin.

Lori oju opo Instagram rẹ ni Chanel ti bẹrẹ si ni fun Oluwo lesi pelu awọn ọrọ ati aworan to le ni ogun, nitori Oluwo sọ ọrọ kubakugbe si.

Chanel Chin pe Oluwo ni okunrin ẹni ọdun marundinlọgọta to n ṣe bi ọmọde.

Ọrọ ti olori ana sọ si Oluwo

Oríṣun àwòrán, hrh.queen.chanel/Instagram

O tun lo fi foto lede nibi ti aayan ti n tiraka lati wọ inu ọkọ, to si fi akọle sori rẹ pe '' ẹ wo Emir Ilẹ Yoruba to n wọ inu ọkọ lati ya ara rẹ ni were''.

Bakan naa lo fi fọtọ iyawo Oluwo tẹlẹ ko to fẹ Chanel lede, eleyi ti o fihan pe Oluwo parọ fun oun pe oun ko ni iyawo ri.

Ko tan si bẹ o, Chanel fi aworan olori tuntun ni aafin Oluwo han, eleyii ti ko i ti han si gbogbo eniyan nitori Oluwo ko i tii kede rẹ.

Ni oju opo Chanel kan naa lo ti fi sọọbu itaja kan lede, ti ko si nkankan ninu rẹ yatọ si milo kan ati peak milk kan pẹlu akọle wi pe '' Ile itaja ti mo si re e fun emi ati Oduduwa pẹlu owo ti Emir Ilẹ Yoruba fun wa.

Ọrọ ti olori ana sọ si Oluwo

Oríṣun àwòrán, Queen Chanel

Bakan naa lo parọwa si awọn ololufẹ rẹ paapaa awọn abilekọ wi pe, ki wọn kọ ọmọ lati ni ifarada, amọ kii ṣe lati gba ki ọkunrin kan ma a na wọn tabi fi iya jẹ wọn.

Ọdun 2019 ni Oluwo ti Iwo ati iyawo re Chanel Chin fi ara wọn silẹ gẹgẹ bi ọkọ ati iyawo lori ẹsun pe oun fi iya jẹ aya rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: