Abortion pills images and names: Ìjọba Texas fòfin de oyún ṣíṣẹ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́fà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Texas, nilẹ Amẹrika ti buwọlu ofin tuntun kan ti ko faye gba awọn obinri lati ṣẹ oyun ti ọjọ ori rẹ ba ti kọja ọsẹ mẹfa.
Ofin tuntun naa sọ pe o ti di eewọ ki wọn ṣẹ oyun lasiko yii nitori ọmọ inu ọhun yoo ti maa mi lasiko naa.
Ofin ọhun to jẹ ọkan gboogi lara ofin to lagbara julọ ni Texas di ofin lẹyin ti ile ọjọ giga ipinlẹ naa kọ lati tẹti si ẹbẹ awọn to maa n ṣẹ oyun.
- Wo ìpínlẹ̀ mọ́kànlá tí ìdaranjẹ̀ ti di èèwọ̀ ní gúúsú Nàíjíríà
- UK ya kúrò lára EU, Yorùbá le yapa lára Nàíjíría tí kò bá sí ìwé òfin tuntun - Gbadamosi, Ilana Omo Oodua
- "Alhaji Fatai, ti DSS pa nílé Sunday Igboho ni kò ríran"
- Irọ́ ní, Taskforce ló ń gba owó gọbọi lọ́wọ́ awakọ̀ Eko, kìí ṣe àwa - LASTMA
- Afurasí ajínigbé dèrò ọrun, òmíràn kó sí pańpẹ́ ọlọ́pàá l’Ogun
- Ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ sí gbangba òde, kóo rugi oyin lábẹ́ òfin tuntun
- Buhari, àbẹ́rẹ́ àjẹsára kàńpá kọ́ ló kàn bí kò ṣe ko kọ́kọ́ mú ara dẹ ìlú - Aráàlú faraya
Ẹwẹ, ọpọ awọn dokita atawọn ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ obinrin ti bu ẹnu atẹ lu ofin tuntun ọhun.
Ofin naa fun awọn eeyan laṣẹ lati pe eyikeyiu dokita to ba ṣẹ oyun ti ọjọ ori rẹ ti le ni ọsẹ mẹfa lẹjọ.
Gomina ipinlẹ Texas, Greg Abbott lo buwọlu ofin naa ti wọn n pe ni "Heartbeat Act."
Ṣugbọn awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan kan bii Planned Parenthood ati American Civil Liberties Union, ACLU, ti ke si ile ẹjọ to ga julọ nilẹ ọhun lati wọgile ofin naa.
ACLU sọ pe ida aadọrun oyun ti wọn n ṣẹ nilẹ Amẹrika ti dagba ju ọsẹ mẹfa lọ, nitori naa, ofin tuntun naa "ko ba ofin mu."
Ile ẹjọ giga naa ṣi lagbara lati da ofin tuntun ti ipinklẹ Texas gba kalẹ yii danu.
Ki lo wa ninu ofin naa?
Lọdun 1973, ile ijọ giga julọ l'Amẹrika sọ pe awọn obinrin le ṣẹ oyun ti oyun naa ko ba tii to oṣu marun un si mẹfa.
Ṣugbọn ofin tuntun ti ipinlẹ Texas yii sọ pe awọn obinrin ko le ṣẹ oyun mọ lẹyin ọsẹ mẹfa, asiko yii si jẹ asiko ti ọpọ obinrin ko tii ni mọ pe oyun ti duro lara awọn.
- Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù mójú lọ sọ́jà, bí kátàkárà agbábọ́ọ́lù ṣe dópin
- Àṣírí tú lórí ìdí tí DSS kò ṣe fi mẹ́rin sílẹ̀ nínú amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho - Amòfin Olajengbesi
- Akeredolu buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro l'Ondo
- Ìmáàmú àgbà kan ní Abuja ti fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí Buhari torí ìkọlù agbébọn
- O kò ní wọ ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí tó ò bá gba abẹ́rẹ́ Covid-19 - Ìjọba Ondo
Ofin tuntun ti Texas yii tun sọ pe araalu le pe ẹnikẹni lẹjọ, niwọn igba ti ẹni naa, yala dokita tabi obinrin, ba ṣẹ oyun lẹyin oṣu mẹfa.
Ẹwẹ, ofin ọhun sọ pe eeyan le ṣẹ oyun lẹyin ọsẹ mẹfa ti ẹmi alaboyun ọhun ba wa ninu ewu.
Wayi o, awọn obinrin ni Texas ti wọn ba fẹ nifẹ si oyun ṣiṣẹ yoo ni lati tẹkọ leti lọ si ipinlẹ miran ti oyun ọhun ba ti le ni oṣu mẹfa.













