Insecurity in Nigeria: Sheikh Nuru Khalid ní kí Buhari wá nǹkan ṣe sí ìkọlù agbébọn bíbẹ́ẹ̀kọ́...

Sheikh Nuru Khalid

Oríṣun àwòrán, Sheikh Nuru Khalid/Femi adesina

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Onimọ ẹsin Islam kan, Sheikh Nuru Khalid ti bu ẹnu atẹ lu iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari lori akitiyan awọn janduku.

Khalid, to jẹ Imaamu agba sọ pe Ọlọrun yoo fiya jẹ Buhari to ba kọ lati da Naijiria pada si bo ṣe wa tẹlẹ.

Imamu naa sọ pe ko si ohun to n jẹ pe awọn janduku n daluru ni Naijiria tẹlẹ, ayafi igba ti Buhari gori alefa.

Lasiko to n ba awọn ọmọ ijọ rẹ sọrọ nibi iwaasu kan, Imaamu naa ni Ọlọrun yoo fiya jẹ Buhari to ba kọ lati pana wahala ti awọn janduku naa n da silẹ.

Ninu fidio iwaasu rẹ kan to n milẹ titi lori ayelujara, o ni "Ẹ lọ sọ fun Buhari pe labẹ iṣejọba rẹ, awọn kan n dunkoko mọ awọn to n gbe ni igberiko, wọn si n fi ipa gba owo lọwọ wọn tabi ki wọn ṣakọlu si wọn."

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

"Lẹyin naa ni ijọba maa ko owo naa jọ, ti wọn a si kede ni gbangba pe awọn yoo san owo ọhun fun awọn jandukun naa."

O tẹsiwaju pe, "Ẹ sọ fun Aarẹ pe apakan orilẹ-ede yii ni tiwa, apakan to ku , awọn janduku lo n ṣakoso rẹ."

"A fẹ ki Aarẹ da orilẹ-ede yii si bo ṣe ba a ki awọn janduku to maa paayan bi ẹni pa ẹran, bi bẹẹ kọ, Ọlọrun yoo fiya jẹ."

Ẹnu oṣu melo kan yii ni awọn janduku bẹrẹ si n ṣọṣẹ ni Naijiria, ti ijọba apapọ ko si ri nnkan ṣe si.

Lara awọn ibi ti awọn janduku naa n kọlu ni, ile ẹkọ atawọn ile ijọsin.

Ọpọ awọn akẹkọọ atawọn olori ẹlẹsin lawọn janduku naa ti ji gbe ti wọn si ti pa lẹyin ti wọn ti kọkọ gba owo itusilẹ wọn tan.

Àkọlé fídíò, Grace Oyin Adejobi: Bí mo bá tún ayé wá, ọkọ mi ni màá padà fẹ́