Ortom: Àwọn Fulani tó fẹ́ gbẹ̀mí mi ní àwọn ló ni gbogbo Nàíjíríà

Samuel Ortom

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, si duro lori ọrọ to sọ pe awọn Fulani daran-daran n gbero lati gba gbogbo ilẹ orilẹ-ede Naijiria.

Gomina Ortom so fún BBC pe oun ni ẹri to daju ti o lè fìdí rẹ múlẹ pe awọn Fulani n gbero lati gba Naijiria.

Ortom ni ẹgbẹ Fulani Nationality Movement, FUNAM ti wọn gbiyanju lati gbẹmi oun, sọ pe awon lo ni gbogbo Naijiria.

FUNAM ni Naijiria nikan ni orile-ede to jẹ ti tawọn. Gomina Benue ni ọrọ naa wa ni akọsilẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Mo ti fi ẹda iwe ti mo kọ ọrọ naa ranṣẹ si aarẹ, awọn ọlọpaa ati ajọ DSS.

FUNAM ni awọn gbiyanju lati jija yii lọdun 1800 laye Usman Danfodio , ṣugbọn kò ṣeeṣe.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni: Bí ìwọ́de Yoruba Nation bá tún wáyé, màá bá wọn kópa níbẹ̀

Won ni agbara wa, owo wa, awọn sí ni ohun tó máa gbà láti gba gbogbo Naijiria," Ortom ṣalaye.

Gomina Ortom ti n tako ìjọba àpapọ lori eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.

O ni ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari fi ọwọ yẹpẹrẹ mu eto abo ni Naijiria.

Ortom ni iroyin igbesunmọmi ti awọn ọmọ Naijiria maa n gbọ lokeere tẹlẹ nipa Afghanístàn, Iraq at'awọn orileede agbaye mii ti wa n ṣẹlẹ ni Naijiria bayii.

"O dàbí ẹni pé ijọba n ṣegbe lẹyin awon janduku adaluru yii, tori ijọba ko sọ ohun kan nipa gbogbo nkan ti o n ṣẹlẹ," gomina Benue lo sọ bẹẹ.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn agbébọn ti yìbọn pa ọmọ sẹ́nétọ̀ kan ní Kaduna

Abdulkarin Bala Ibn Na'allah

Oríṣun àwòrán, others

Awọn agbebọn ti ṣekupa akọbi ọmọ sẹnetọ to n ṣoju ẹkun ila oorun Kebbi nile igbimọ aṣofin agba, Abdulkarim Bala Na'allah.

Oloogbe naa, to jẹ awakọ ọfurufu ni wọn pa nile rẹ to wa lagbegbe Malali niluu Kaduna.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, ASP Muhammad Jalige ṣalaye fun BBC pe awọn agbebọn naa gbe ọkọ oloogbe ọhun lọ lẹyin ti wọn gbẹmi rẹ tan.

O ni "Lootọ ni awọn agbebọn ti yinbọn pa ọmọ sẹnetọ naa nile rẹ lagbegba Malali ni irọlẹ ọjọ Aiku ti wọn si gbe ọkọ rẹ lọ."

"Ṣugbọn nigba ti wọn lọ sibi ti iyawo rẹ wa, ko si nible tọkọ-taya naa ko si tii bi ọmọ."

Iku ọmọ sẹnetọ yii lo waye lẹyin ti awọn agbebọn ti kọkọ n ṣekupa awọn eeyan mii nipinlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Rape survivor: Ìyá mi ni ń kò gbọdọ̀ sọ̀rs kí ilé má bà á dàrú- Oluwatobi Raji

Lọjọ Abamẹta, awọn agbebọn ṣekupa eeyan meji ni abule Makoro to wa ni ijọba ibilẹ Kajuru, nipinlẹ Kaduna yii kan naa.

Kọmiṣọna fun ọrọ eto abo abẹle, Samuel Aruwan sọ fun awọn akọroyin pe awọn agbebọn ọhun yabo abule naa ki wọn to ṣekupa awọn eeyan meji ọhun to fi orukọ wọn lede gẹgẹ bii Gideon Mumini ati Barnabas Ezra.

Ẹwẹ, ori ko awọn arinrinajo mẹta kan yọ lọwọ awọn agbebọn loju ọna Gidan Waya-Godogodo ni ijọba ibilẹ Jema ni ipinlẹ yiin kan naa lọsẹ to kọja.