2023 Presidency: Àlàyé Ameachi rèé lórí bóyá lóòtọ́ ni àjọsọ wà láàrin Tinubu àti Buhari nìpa ìbò 2023

Bola Ahmed Tinubu and Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, The Presidency

Mínísíta tó ń rí sí ètò ìrìnà àti iṣẹ́ òde ni Nàìjíríà tí fèsì sí ọ̀rọ̀ tó gbòde pé ààrẹ Muhammadu Buhari àti Asíwájú Bola Ahmed Tinubu ní àdéhùn tí wọ́n ṣe fún ipò ààrẹ ọdún 2023.

Ọ̀rọ̀ náà ló tí ń tàn ká láti ọdún 2015, kí ìdìbò ààrẹ to wáyé.

Àwọn kan sọ pé ẹgbẹ́ All Progressives Congress (APC) yọ Tinubu gẹ́gẹ́ bí oludije fun ìgbàkejì ààrẹ fún Buhari nítorí awuyewuye pé musulumi ati musumi kò lè di ààrẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn ni èyí sì lo mú kí Buhari fi ọkàn Tinubu balẹ̀ pe oun ni yoo gba ijọba lọdun 2023.

Èyí ló mú kí àwọn gómìnà ìhà Gúúsù àti àwọn olóyè ẹgbẹ́ òṣèlú People Democratic Party (PDP) bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ẹ̀sùn kan APC pé wọ́n yí Nàìjíríà sí orílẹ̀-èdè Musulumi.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ péjọ láti rọ Tinubu, tí wọ́n sì ni kí o mú ẹni tí yóò jẹ ìgbàkejì fún Buhari wa.

Lẹ́yìn èyí, ni wọ́n yan kọmísọ́nà ètò ìdájọ́ nípìnlẹ̀ Eko nígbà kan rí, Yemi Osinbajo si ipo igbakeji aarẹ, tí wọ́n sì já Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Kayode Fayemi sílẹ̀.

Ṣùgbọ́n ṣáájú ìdìbò ọdún 2019, ìròyìn sọ pé ààrẹ túbọ̀ fi dá Jagaban lójú pé òun ni yóò gba ipò lọ́dún 2023.

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, wọn ni Tinubu ransẹ́ pé Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tẹ́lẹ̀rí, Bisi Akande láti wá sìn òun lọ sí ilé iṣẹ́ ààrẹ fún àbẹ̀wò.

Làsìkò yìí gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọy, ní Tinubu tún ní kí ààrẹ Buhari tún ìlérí rẹ̀ ṣe, tí ààrẹ sì tún fọwọ́ sọ̀yà pé kódà bójú bá yẹjú, ohùn kò ní yẹ̀.

Ìgbàgbọ́ ni pé ìpàdé èyí wáyé nínú oṣù kíní ọdún 2018.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Alaye Amaechi ree lori adehun Buhari si Tinubu taye n pariwo:

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ yii pẹlu iwe iroyin Daily Trust, Rotimi Amaechi ṣàlàyé pé òun kò ní ànfàní láti mọ kókó tó wà nínú àdéhùn wọn.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers nígbà kan rí ọhun ni, kò si ìdánilójú pé Buhari àti Tinubu ṣe irú ìpàdé ìdákọ́nkọ́ tó jọ bẹ́ẹ̀.

Ó fi kun pé òun gẹ́gẹ́ bí adarí gbogboogbò fún ìpolongo ẹgbẹ́ APC, kò sí àsìkò kankan tí òun péjú síbi irú ìpàdé bẹ́ẹ̀.

"Ṣùgbọ́n tí ó bá wá jẹ́ pé ìpàdé ìdákọ́nkọ́ wáyé láàárín ààrẹ Buhari àti Asiwaju Ahmed Tinubu, òun kò mọ̀."

" Tí ó bá jẹ́ pé ìpàdé ìtagbangba tí ẹgbẹ́ APC pè, tí mi ò sì sí níbẹ̀ ajẹ́ wípé nǹkan mìíràn wà níbẹ̀ nìyẹn.

Amaechi fi kún pé òun kò gbọ́ ìgbà kankan tí wọ́n sọ pé kí wọ́n gbé ìjọba fún Tinubu lọ́dún 2023.

Amin iyasọtọ kan

Tinubu jẹ́ atọ́nà àti aláànú ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà - Olórí aṣòfin Eko

Bola Tinubu ati Mudasiru Obasa

Oríṣun àwòrán, Mudasiru Obasa

Ọmọ ilé igbimọ̀ asòfin ni ìpínlẹ̀ Eko ni a síwájú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) Bola Ahmed Tinubu mú ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ni òkúnkúndùn

Agbenusọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin Eko ìpínlẹ̀ Eko Mudashiru Obasa lo sọ èyí lẹ́yìn tí òhun àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ tó kù rin ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè láti lọ sàbẹ̀wò sí Asiwaju Ahmed Tinubu

Ó ní kokoko ni ara Asiwaju le, ti ko si si amin pe o n se ojojo kankan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Díẹ̀ lára àwọn tó sàbẹ̀wò sí Bola Ahmed Tinubu ni alága ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó lórí ìgbòkègbodò ọkọ̀ Temitope Adewale, alága ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó lórí ètò ìlú àti àyíká Nureni Akindanya àti alága tẹ̀ẹ́kótó lórí ètò ọ̀rọ̀ ajé ilẹ̀ òkèrè Sylvester Ogunkelu.

Àkọlé fídíò, Thyroid foundation: eéwo ni mo kọ́ka pè é àṣé gẹ̀gẹ̀ ọrùn tó lé ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ni mo n

Obasa ni bí Tinubu ṣe máa ń dẹ́rìn pa àwọn ènìyàn náà lọ sì ń ṣe àti pé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ láàrin àwọn tó jọ kọ́wọ̀ọ́rin wáyé lórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè Nàìjíríà.

Ó ní abẹ̀wo náà ṣe pàtàkì nítorí ipò Tinubu gẹ́gẹ́ bí aṣáájú lórílẹ̀ - èdè yìí, ó jẹ́ atọ̀nà fún ọ̀pọ̀ àti aláànú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Agbẹnusọ ilé sọ pé :" Ọ̀rọ̀ Nàìjíríà jẹ a síwájú gidi gan. Kokoko ni ara rẹ̀ lè a sì ni ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó pọ̀ gidi gan pàápàá jùlọ lórí ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Inu rẹ̀ dùn gidi, ó ṣe àwàdà bí ó ṣe máa ń ṣe bákan náà sì ni ó ní ìgbàgbọ́ nípa ìlọsíwájú Nàìjíríà "

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí