Alaafin: Àwọn oríadé fún Oba Adeyemi lésì lórí agbára ìfoyè dánilọ́lá nílẹ̀ Yorùbá tó gbé wọ ara rẹ̀

Ooni ati Alaafin n ki ara wọn

Oríṣun àwòrán, other

Ni ọjọ diẹ sẹyin ni Alaafin tilu Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta kede pe oun nikan ni ọba alaye nilẹ Yoruba to ni ẹtọ lati fi oye to kan gbogbo ilẹ Yoruba da eeyan pataki lọla.

Nibi ayẹyẹ ifinijoye Babajide Agunbiade ati Asofin Shina Peller gẹgẹ bi Atọbaṣe ati Ayedẹrọ ilẹ Yoruba ni Ọba Adeyẹmi ti sọ ọrọ naa.

Lẹyin to sọ ọrọ ni ọpọ awọn ọmọ Kootu Oojire ti rọ si ori ayelujara lati maa fi oniruuru ero wọn han lori rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọna ati mọ bi ọrọ ṣe jẹ, BBC News Yoruba tọ awọn agbagba ilẹ Yoruba kan lọ fun alaye ati ilanilọyẹ lori rẹ lati mọ boya lootọ Alaafin nikan lo ni ẹtọ lati maa fi awọn eeyan jankan jẹ fun oye to wa fun gbogbo ilẹ Yoruba lapapọ.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Ọrọ Alaafin ri bẹẹ, ko si tun ri bẹẹ tori igba ti yi pada - Olugbọn

Ninu ọrọ tirẹ Kabiyesi Olugbọn ti ilu Ile Igbọn, Oba Francis Olushola Alao ṣalaye pe, bameji lọrọ Alaafin naa ja si. Bi eeyan ṣe le sọ pe ododo ọrọ ni Baba Alaafin sọ, ni eeyan tun lee sọ pe ko ri bẹẹ.

Kabiyesi Olugbọn ni lọpọlọpọ ọdun sẹyin, ijọba ilẹ Ọyọ tan ka ọpọlọpọ ilẹ Kootu Ojiirebi titi de ilẹ Dahomey to jẹ orilẹede Benin Republic bayii.

Ṣugbọn o ni nnkan ti yi pada, ijọba orilẹede Naijiria ti pin ilu si ipinlẹ, ti wọn si ti fi awọn ọba alaye kan ṣe olori nibẹ.

Ọba Alao ni ko yẹ ki ọrọ ariyanjiyan o maa waye lori awọn nnkan wọnyii mọ nilẹ Yoruba nitori pe nibi ti Eleduwa kẹ Baba Alaafin de, ko si ibi ti wọn ko le yan si nilẹ Yoruba, ṣugbọn nnkan ti yipada pẹlu awọn ipinlẹ si ipinlẹ.

Àkọlé fídíò, Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ

Kabiyesi Ọba Adetokunbọ Tẹjuoṣo, Olu ti ilu Kemta ni asiko to fun awọn eekan ọba nilẹ Yoruba lati mu awọn iwe ijọba gbogbo to ba tọ jade lati fi yanju awọn ariyanjiyan kan ti o n figba gbogbo suyọ.

O ni eyi yoo jẹ ki gbogbo awọn iran to n bọ lẹyin wọn lee mọ ẹwẹ yatọ si owe lori ọrọ oye jijẹ nilẹ Kootu oo jiire.

Ki ni aafin ile Oodua sọ nipa ọrọ yii?

Ninu ọrọ tirẹ, Kabiyesi Lọwa Adimula ti ilẹ Ifẹ, o ṣalaye pe ọrọ ko ri bi Kabiyesi Iku Baba yeye Alaafin ilu Ọyọ ṣe sọ rara ati pe, 'aifagba fẹnikan ti ko jẹ kaye o gun, lo n damu iran Yoruba.'

Kabiyesi Lọwa Adimula ni niwọn igba ti Baba Alaafin ko ti jiyan pe ọmọ Ọranmiyan ni oun jẹ, to si jẹ pe Ile Ifẹ ni Ọranmiyan ti ṣẹ wa, to si fi igba kan ri jẹ Ọọni nilu Ile Ifẹ.

O ni gẹgẹ bi Arole Oduduwa, Ọọni lo ni gbogbo ohun ti Oduduwa fi silẹ saye, iyawo ni o, ọmọ ni o, ilẹ ni o tabi ile.

Àkọlé fídíò, Onpetu Ijeru: Akala ní torí Aláàfin kò ṣúgbàá òun fún sáà kejì, ló ṣe ní kí pín ipò alága

O ni emi o ju ọ, iwọ o ju mi ni ko jẹ ki ilẹ Yoruba to tabi gun rege nitoripe olukuluku to n sọ itan si ibi to wu u.

"Baba Ọọni, Arole Oduduwa ni, akọbi Oduduwa. Oun dẹ lo jogun gbogbo ade to wa laarin gbogbo kootu oo jiire nibikibi ti wọn ba ti n de ade nitori Oduduwa lo ni ade, oduduwa lo si bi Ọranmiyan.

Mi o wa mọ bi ọmọ-ọmọ yoo ṣe wa maa sọ pe oun ju ẹgbọn Baba oun lọ.

Kabiyesi Lọwa Adimula ilẹ Ifẹ, ṣalaye pe titi di oni ko si Alaafin ti yoo jẹ ti ko ni wa si idi ọpa Ọranmiyan nilu Ile Ifẹ lati wa gba Ida.

O ni o si tun ni ohun ti Ifẹ maa fun un lọ gẹgẹ bii Lọwa Adimula ati pe eyi ko si yọ Alaafin to wa lori oye bayii silẹ, ti akọsilẹ rẹ si n bẹ ni ile Oduduwa nilu Ile Ifẹ.

Bi Alaafin ba fi eeyan joye Yoruba, ilu Oyo nikan lo mọ - Onpitan

Aarẹ Opitan ilẹ Ibadan, Oloye Laji Abass naa da si ọrọ ọhun.

O ni otitọ ọrọ ni Kabiyesi Alaafin sọ nipa pe awọn nikan lo lee fi eeyan jẹ oye to kaari ilẹ Yoruba.

Amọṣa o yan an pe, iyatọ gedegbe lo wa laarin Yoruba ati Ilẹ Oodua.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Ẹyin naa pe haha. Aarẹ Opitan ilẹ Ibadan Oloye Laji Abass ṣalaye pe, ipade ti awọn oyinbo amunisin pe lọdun 1919 nilu Ibadan ni wọn ti mu aba wa pe ki wọn maa pe gbogbo iran ọmọ oduduwa ni Yoruba nitori irọrun iṣakoso ati awọn idi miran.

O fi kun un pe Kabiyesi Ọọni igba naa, Ọọni Ademiluyi kọ jalẹ lori eyi nitori o ni yoo pa orukọ awọn ẹya yoku bii Ijẹṣa, Igbomina, Awori, Owu ati bẹẹ bẹẹ lọ rẹ.

Nitori ṣaaju asiko naa, awọn ilu Ọyọ ni wọn n pe ni Yoruba.

O ni nitori naa, bi Alaafin ba fi eeyan jẹ Oye le Yoruba lori o lẹtọ ṣugbọn irufẹ ẹni bẹẹ ko lee de ilẹ Ijẹṣa, tabi Igbomina to jẹ Ilẹ awọn Owu.

Bakan naa ni ko le de Ẹgba ti Alake n ṣolori fun atawọn ilẹ Oodua yoku, lati maa pe ara rẹ ni Oloye nibẹ.

"Bi Kabiyesi Ọwa ilẹ Ijẹṣa ba fi eeyan jẹ, ilẹ Ijẹsa ni wọn yoo pe, kii ṣe ilẹ Yoruba. Bi baba wa Awujalẹ ba fi eeyan joye, oye ilẹ Ijẹbu ni wọn yoo pe kii ṣe gbogbo ilẹ Yoruba, bẹẹ naa ni Alake ilẹ Ẹgba ati Ọọni ile Ifẹ.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Ohun ti awọn eeyan ko mọ ni pe Ọyọ ni Yoruba. Ko si eeyan kan to lee fi eeyan joye to ba jẹmọ Yoruba laye bi ko ṣe Alaafin Ọyọ nitori awọn ni wọn ni orukọ yẹn. Ọyọ alaafin nikan nii jẹ Yoruba"

Oloye Abass ni bi Alaafin ba fi eeyan jẹ Oye kan to pee ni ti ilẹ Yoruba, fun apẹrẹ, Aarẹ Ọna kankanfo ti Iba Gani Adams jẹ, labẹ Alaafin Ọyọ ni oye bẹẹ si mọ.

O ni Oduduwa lo bi Ọranmiyan ti awọn ẹya ọmọ rẹ n jẹ Yoruba, ṣugbọn awọn ọmọ miran wa ti oduduwa bi.

Bi awọn Ọyọ ṣe n jẹ Yoruba ni awọn iran Ọrangun ile Ila naa jẹ Igbomina, awọn Ẹgba n jẹ Ẹgba. Gbogbo awọn ẹya wọnyii lo wa tọpasẹ okun iṣẹdalẹ wọn pada si ilu Ile Ifẹ lọdọ Oduduwa.

Bẹẹ ni gbogbo awọn to wa nilẹ kootu oo jiire bayii ni wọn jẹ ọmọ Oduduwa.

Amin iyasọtọ kan

Èmi nìkan ni ọba tó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi oyè ilẹ̀ Yorùbá dá èèyàn ńlá lọ́lá - Alaafin

Oba Lamidi Adeyemi III

Oríṣun àwòrán, alaafin_oyo

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, Alaafin tilu Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ti kede pe oun nikan ni ọba alaye nilẹ Yoruba to ni ẹtọ lati fi oye to kan gbogbo ilẹ Yoruba da eeyan pataki lọla.

Alafin, lo sisọ loju ọrọ yii lasiko to n fi oye Atobase ati Ayedero da Babajide Agunbiade ati Asofin Shina Peller lọla lopin ọsẹ.

Ọba Adeyemi ni laarin awọn ọba to wa nilẹ Kaarọ Oojire, oun ni ojuse yii wa nikawọ rẹ lati se, eyi tii se fifi oye ilẹ Yoruba da awọn ẹni nlanla lọla.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Lati igba ti alaye ti daye, emi ni ọba ati ori fun orilẹede Yoruba.

Emi ni ọba to maa n fi oye pataki da awọn ẹni pataki lọla, lọkunrin ati lobinrin, yika gbogbo ilẹ Oduduwa.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Ni ọna ati se ojuse wọn yii, gbogbo Alaafin to ba n jẹ ni wọn maa n tọ sọna nidi yiyan awọn ọmọ Yoruba pataki lati fi oye to kan gbogbo ilẹ Yoruba da awsn lọla."

Bakan naa ni oriade ọhun tun salaye pe oun fi oye da awọn eeyan pataki mejeeji naa lọla nitori pe wọn jẹ ojulowo ati amuyangan ọmọ Yoruba.

Alaafin ni awọn asa ati ohun ajogunba wa ni ohun amuyangan fun iran Yoruba gẹgẹ bi oun se maa n sọ kaakiri ni gbogbo igba.

O ni iran Yoruba ni awọn ofin aatẹle to pegede ti wọn ko kọ silẹ rara, ti ọpọ eeyan si maa n tẹle lọna to lagbara.

"Awọn oye wa ni opo to gbe iran Yoruba ro, ipilẹ ilana isejọba wa, nitori naa ni ọba alaye kan le se bo se wu lai ri ipa rẹ lara lẹyin o rẹyin.

Idi si ree ti ọba alaye fi gbọdọ se ijọba nibamu pẹlu awọn asa ati ise to wa nilẹ Yoruba."

Amin iyasọtọ kan

Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ lo okun yín fún ìdàgbàsókè Naijiria bíi ti àwọn Awolowo àti Akintola - Alaafin

Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi

Oríṣun àwòrán, alaafin_oyo

Saaju la ti sọ fun yin pe, Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta ti ke si awọn ọdọ Naijiri lati lo okun wọn gẹgẹ bii ọdọ fun igbedide ati idagbasoke Naijiria.

Ọba Adeyemi ni ọdọ ni awọn eeyan bi Obafemi Awolowo, Ahmadu Bello ati Samuel Akintola nigba ti wọn ṣe gudugudu meje ati yaya mẹfa lati tun Naijiria ṣe.

Alaafin lo sọ ọrọ naa nibi iwuye Shina Peller ati iyawo rẹ, Ayobola gẹgẹ bii Ayedero ati Yeye Ayedero ilẹ Yoruba.

Bakan naa ni Alaafin tun fi amojuẹrọ Jide Agunbiade ati iyawo rẹ joye Atobaṣe ilẹ Yoruba.

Alaafin sọ pe "Lati igba iwasẹ ni Alaafin ti jẹ ori nilẹ Yoruba, oun si ni ọba kan ṣoṣo nilẹ Yoruba to le fi eeyan to tọ joye ni gbogbo ilẹ Yoruba."

O sọ siwaju si pe ẹnikẹni ti yoo ba joye ti yoo jẹ itẹwọgba ni gbogbo ilẹ Yoruba gbọdọ jẹ ẹni ti iwa rẹ jọju.

Àkọlé fídíò, Thyroid foundation: eéwo ni mo kọ́ka pè é àṣé gẹ̀gẹ̀ ọrùn tó lé ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ni mo n

Nigba to n sọrọ, Shina Peller, to n ṣoju ẹkun idibo Iseyin, Itesiwaju, Iwajowa ati Kajola nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja fi ẹmi imoore han si Alaafin, o si ṣeleri pe oun ko ni ja ori ade naa kulẹ.

Lara awọn eekan ilu to wa nibi iwuye naa ni gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Otunba Alao Akala, igbakeji gomina tẹlẹ, Oloye Moses Alake, ati Ọba Adekunle Adebowale to ṣoju fun Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi.

Awọn eekan ilu mii to tun wa nibẹ ni igbakeji gomina tẹlẹ, Kolapo Eleka, igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo,Oloye Olalekan Alake, alufaa Ayo Ladigbolu, atawọn eeyan jankan jankan miran.

Àkọlé fídíò, Rape survivor: Ìyá mi ni ń kò gbọdọ̀ sọ̀rs kí ilé má bà á dàrú- Oluwatobi Raji