Oba Ogboni: Bí ìwọ́de Yoruba Nation bá tún wáyé, màá bá wọn kópa níbẹ̀
Ọba Ogboni Abalaye, Tajudeen Bakare ti salaye awọn ohun to sẹlẹ ni ahamọ ọlọpaa lasiko ti wọn mu pe o se iwọde Yoruba Nation.
Ọba Ogboni lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ kede pe kii se pe oun yi awọn ọrọ ti oun sọ lasiko iwọde pada lẹyin ti awọn ọlọpaa mu oun tan gẹgẹ bi awọn kan se n sọ kiri.
O fikun pe ohun to sẹlẹ laarin ọjọ kẹta si ikẹrin osu Keje ọdun yii tawọn ọlọpaa mu oun pe oun se iwọde, to ba sẹlẹ si ẹlomiran, yoo ti ku.
- Olùwọ́de 47 nínú àwọn tí ọlọ́pàá kó ní ìwọ́de Yoruba Nation ti gba ìtúsílẹ̀ láhámọ́ ọlọ́pàá
- Buhari, tètè mú ọ̀kan nínú ìdásílẹ̀ Yoruba Nation àbí ìjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn - Gani Adams
- Ààrẹ Ògbóni sọ òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Gani Adams torí bó ṣe tàbùkù Ọba Ogboni tó ṣe ìwọ́de Yorùbá Nation
- Ilé ẹjọ Májísírèètì Yaba nípinlẹ Eko ti gba béèlì àwọn olùwọde Yoruba Nations 49 tí wọn wa ní àhámọ
- Bàbá ni Alake Ẹgba jẹ́ fún mi, mi ò lè ṣe ìkọlù sí ààfin rẹ̀ - Igboho
- Ìjọba Eko jáwọ́ nínú ẹ̀sùn tó fi kan Ọba Ogboni pé ó pààyàn ní ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota
"Kii se pe mo yi ohun ti mo sọ nibi iwọde pada nigba ti mo de agọ ọlọpaa, amọ ohun ti oju mi ri laarin ọjọ kan sira wọn ni agọ ọlọpaa, ni mo fi tun ọrọ miran sọ.
Mọja mọsa laa mọ akikanju loju ogun, ko ni dara ki ẹni to sọ pe oun n ja fun ilu, gba lati ku, idi ree ti mo fi sọ nnkan miran, mo si duro lori ohun ti mo gbagbọ.
To ba jẹ pe ẹlomiran ni isẹlẹ naa sẹlẹ si, laarin ọjọ Kẹta osu keje ti ọlọpaa fi mi si ahamọ si ọjọ Kẹrin osu kẹjọ ti wọn fi mi silẹ, onitọun yoo ti ku tabi yi ohun to sọ pada."
Nigba to n fesi lori iwoye awọn araalu pe ojo ni ati pe o yẹ ko poora mọ awọn ọlọpaa lọwọ ni, to ba jẹ pe lootọ lo jẹ Ọba Ogboni, Bakare ni ootọ ni ohun ti wọn sọ.
Amọ o ni eeyan mẹfa lo wa ninu mọto pẹlu oun lasiko ti ọlọpaa mu awọn, ti awọn eeyan naa kii si se ọmọ ẹgbẹ awo Ogboni.
Alaye ree lori idi ti n ko fi poora ni ahamọ ọlọpaa:
O ni ti oun ba wa poora, ti awọn yoku si wa ni ahamọ ọlọpaa, ki ni yoo jẹ ipin wọn, idi si ree ti ohun ko fi poora lọna ati daabo bo awọn eeyan ti wsn mu pẹlu oun.
Ọba Ogboni ni oun ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ipaniyan tawọn ọlọpaa pada fi kan oun nitori wọn ko ba ibọn lara oun lọjọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èmi nìkan ni ọba tó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi oyè ilẹ̀ Yorùbá dá èèyàn ńlá lọ́lá - Alaafin
- Wo àṣírí márùn-ún tí obìnrin kò gbọdọ̀ sọ fún ọkọ rẹ̀
- Ọjà títà, ọ̀kadà gígùn àti epo títà dèèwọ̀ ní Zamfara torí ọṣẹ́ ajínigbé, agbébọn
- Àwọn agbébọn ti yìbọn pa ọmọ sẹ́nétọ̀ kan ní Kaduna
- Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ lo okun yín fún ìdàgbàsókè Naijiria bíi ti àwọn Awolowo àti Akintola - Alaafin
- Amotekun mú afurasí ajínigbé mẹ́rin lọ́nà Iseyin sí Oyo
- Nàíjíríà ń wó lọ o, Obasanjo, Babangida, ẹ má wo Nàìjíríà níran - Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Arewa figbe ta
- Gómìnà mẹ́ta láti Òkè Ọya ń dírẹ̀ẹ́bẹ̀ lọ́dọ̀ àgbà Yorùbá fún Buhari
"Kii se ibi iwọde Yoruba Nation ni wọn ti mu wa, bẹẹ ni n ko pa eeyan kankan abi bawo ni ẹni ti ko ni ibọn se le pa eeyan?
Amọ ohun to yẹ ko ye araalu ni pe awọn ọlọpaa ko fi iya jẹ mi ni ahamọ sugbọn awọn nnkan wa to ju pe ki wọn fi iya jẹ eeyan lọ, eyi to sẹlẹ si mi ni ahamọ.
Sugbọn gbogbo eleyi ko yi ipinnu mi lati ja fun ilẹ Yoruba pada nitori bi iwọde miran ba tun waye, a jọ maa se ni.
Ọmọ Yoruba ni mi, mo si ti se ileri niwaju awọn alalẹ pe maa ti iran Yoruba lẹyin, nitori naa, ko si ihalẹ tabi idunkooko kankan to le mu mi yi ipinnu mi pada."
Awọn alalẹ lo fi emi ati Sunday Igboho pamọ:
Bakan naa ni Ọba Ogboni Abalaye kede pe ahamọ ti oun wa awọn alalẹ lo fi oun pamọ nitori ibi to le fẹ sẹlẹ si ohun, ka ni oun ko si ni ahamọ ni.
"Sunday Igboho to wa ni ahamọ ni Cotonou, awsn alalẹ lo fi pamọ sibẹ, ko le wa laye, ki ọpọ ewu si le re kọja lori rẹ lo se wa nibi to wa.
Awọn alalẹ lo fi emi naa pamọ lasiko ti mo wa ni ahamọ ọlọpaa, tori naa ni n ko se ni dakẹ fun ijagudu fun ominira ilẹ Yoruba.




















