Yoruba Nation rally agitators: Wọn ti gba oníduró àwọn ènìyàn mọkàndínláàdọta tí wọn kópa nínú ìwọde Yoruba Nation ní Ojota

Eniyan mọkandinlaadota ti ọwọ awọn agbofinro tẹ nipinlẹ Eko nibi iwọde awọn ti wọn n jijangbara fun orile-ede Oduduwa ni ileejó Majisireeti kan ni Yaba nipinle Eko ti gba beeli wọn
Amofin to n gbeja ẹtọ awọn eniyan kan, Olasupo Ojo ati Oladapo Kolade lo saaju ikọ awọn agbẹjọrọ to gbe ẹjọ naa jade.
Die lara awọn ti wọn gba beeli rẹ ni: Olasunkanmi Tanimola; Kabiru Lawanson; Chinemerem Emmanuel; Rasaki Musibau; Lukman Olalade; Olasanmi Oladipupo; Bashiru Shittu; Taofeek Abdusalam; Olamilekan Abata; Abdullahi Sikiru; Tosin Adeleye; Babatunde Lawal.

Oríṣun àwòrán, Ilana Omo Oodua/Facebook
- Ẹ̀yin ọmọ Nàíjíríà, mó rí ìlàkàkà yín, ẹ ṣe sùúrù nítórí ìyá yìí yóò dópìn - Ààrẹ Buhari
- Obìnrin tí kò bá lè mọ rírì owó péréte tí o bá ń fun un kìí ṣe ẹni tó yẹ kí o gbé sílé- Kenneth Okonkwo
- Ààrẹ Ògbóni sọ òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Gani Adams torí bó ṣe tàbùkù Ọba Ogboni tó ṣe ìwọ́de Yorùbá Nation
- Ohun márùn ún tó mú ìgbé ayé le fọ́mọ Nàìjíríà lójoojúmọ́
Awọn mii ni: Taiwo, Adagunodo Babatunde, Oluwafemi Adeleye, Oloye Taiwo, Saheed Kareem, Adebayo Waheed, Akinbode Sunday, Lawal Akeem, Samuel Ire, Ogundile Dare, Oba Tajudeen Bakare.

Ogbeni Maxwell Adeleye to jẹ agbenusọ fun Ilana omo Oodua salaye ninu atejade to fi sita loni ójọ Aje pe egberun lọna ọọdunrun naira ni ki eni kọọkan san pẹlu Oniduro meji.
Adeleye ni pe oniduro kan gbọdọ jẹ ẹbi ẹni naa ki ẹnikeji jẹ Alufaa, Imam, tabi agba adugbo to n san owo ori rẹ deede.









