Kenneth Okonkwo: Obìnrin tí kò bá lè mọ rírì owó péréte tí o bá ń fun un kìí ṣe ẹni tó yẹ kí o gbé sílé

Oríṣun àwòrán, @Okonkwo
Agbaọjẹ oṣere tiata Nollywood, Kenneth Okonkwo, ti ke si awọn ọdọ lati ṣọra fun awọn obinrin ti ko mọ iyi nnkan diẹ ti awọn ololufẹ wọn n fun wọn.
Lasiko to n sọrọ loju opo Facebook rẹ, Okonkwo ni obinrin to ba fẹran ololufẹ rẹ denu ko ni maa tii lati na ọwọ si ohun ti ọwọ rẹ ko ka.
O ni obinrin to ba nifẹ ololufẹ tabi ọkọ rẹ yoo maa ṣatilẹyin fun ni lọna ati mu ala rẹ ṣẹ, dipo ko maa ti i lati ṣe ohun ti ipa rẹ ko ka.
- Ẹ̀yin ọmọ Nàíjíríà, mó rí ìlàkàkà yín, ẹ ṣe sùúrù nítórí ìyá yìí yóò dópìn - Ààrẹ Buhari
- Agbébọn já bàálù ológun bọ́, orí kó Abayomi Dairo, awakọ̀ bàálù náà yọ
- Mó ṣèlérí láti buwọ́lu àtúntò Naijiria, Ilé Aṣòfin o kù sí ọwọ́ yín - Ààrẹ́ Buhari
- Èèyàn kan ti kú, 99 di àwátì lẹ́yìn tí ilé alájà méjìlá wó lulẹ̀ l'óru
- Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ń ṣelédè lẹ́yìn Ajimobi, èrò wọn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀!
- Ọmọ ọdún méje ni mo ti ń digunjalè, ogun ìdílé ló fàá, afurasí ṣàlàyé l'Ondo
- A bẹ Seyi Makinde kó wá nǹkan fún àwọn jàńdùkú adàlúrú àmọ́ kò gbà - Mọgaji Moshood
- Wo iléẹ̀kọ́ tí wọ́n kò ti fààyè gba akẹ́kọ̀ọ́ láti padà sọ́dọ̀ Òbí tàbí ìlú rẹ̀ lẹ́yìn tó bá parí
Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Ki ọlọkada to le pa igba naira, yoo ni lati rinrinajo bii igba mẹrin, sibẹ, ko ni le jere igba naira nitori yoo ni lati kọkọ yọ owo epo ati owo awọn Union kuro ninu owo to pa."
"To n tumọ si pe owo nla ni igba naira yoo jẹ si irufẹ ẹni bẹẹ."
"Ẹ gbọ o, obinrin ti ko ba le mọ riri owo perete to n ba n fun un kii ṣe ẹni to yẹ ki o gbe sile."
Agba oṣere naa ṣalaye pe irufẹ obinrin bẹẹ kii ṣe irufẹ ẹni ti eeyan le ba dagba pọ, o si dara ki eeyan tete yẹra fun irufẹ awọn obinrin bẹẹ nitori ilera ọpọlọ rẹ.
Kenneth Okonkwo sọ siwaju pe o san ki eeyan fẹ obinrin ti ko kawe ṣugbọn to fi ọkan rẹ balẹ ju ki eeyan fẹ alakọwe ti yoo maa ko ọkan rẹ soke lọ.
- Àwọn lọ́balọ́ba nílẹ̀ Yoruba dalẹ̀ wa lórí àwọn ọmọ OPC mẹ́ta tí wọ́n tímólé láìṣẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Iskilu Wakili - Ẹgbẹ́ OPC
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ ẹni méjì tó lọ́wọ́ nínú àgbo tó pa ẹni mẹ́wàá ní Kwara
- Ilé ẹjọ́ gba béèlì Baba Ijesha N2Miliọ̀nù ní wọ́n fún
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo àti àwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ láti fí opin sí ìṣoro ètò aàbò
O ni "Iṣoro to wa nibẹ kii ṣe pe o ko fun ni owo lasiko to yẹ, ṣugbọn ko si iye owo ti o ba fun irufẹ obinrin bẹẹ ti yoo tẹ lọrun.""Eyii to n tumọ si pe o kan n fi owo ati akoko rẹ ṣofo pẹlu obinrin ti ko yẹ ni."Kenneth Okonkwo pari ọrọ rẹ pe ki awọn okunrin maṣe ni ara wọn lara lati tẹ obinrin lọrun nigba ti wọn ko le ṣe ohun kan naa fun ara wọn.Lẹyin naa lo ni "Obinrin to ba fẹran rẹ denu ko ni ti ọ lati kọja aye rẹ, ṣe ni yoo kin ọ lẹyin ki ọjọ ọla rẹ le dara."













