Military Plane Crash: Iléeṣẹ́ ológun ní lóòtọ́ọ́ ní agbébọn já bàálù òun lulẹ̀

Awakọ baalu to ja laarin awọn ọga ologun

Oríṣun àwòrán, NAF

Ileesẹ ologun ofurufu ni Naijiria ti doola ẹmi awakọ ofurufu fun ileesẹ ologun oju ofurufu, Abayomi Dairo lọwọ ọta ibọn tawọn adunkookomọni yin mọ baalu ofurufu ologun ti wọn ja walẹ nipinlẹ Zamfara.

Oludari ẹka alarina ati eto iroyin fun ileesẹ ologun ofurufu, Edward Gabkwetto fidi isẹlẹ baalu to ja naa mulẹ lọjọ Aje ni Dairo n pada bọ nibi to ti lọ sisẹ kan laarin aala ilẹ Zamfara si Kaduna, ni wsn kọlu baalu rẹ naa, to si ja lulẹ.

O ni ori ko Dairo yọ nigba to raye kuro ninu baalu naa ko to ja lulẹ, bi awakọ ofurufu naa si se de ilẹ, ni awọn agbebọn naa gba ya a.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gabkwet ni " Ọjọ Aiku, ọjọ Kejidinlogun osu Keje ọdun 2021 ni deede aago kan ku isẹju mẹẹdogun ni isẹlẹ naa waye.

Ọgagun Dairo to wa ọkọ ofurufu naa lo gbogbo idanilẹkọ lati gba ara ẹni silẹ loju ija to ti ni, lati doola ẹmi ara rẹ.

Awakọ baalu to ja laarin awọn ọga ologun

Oríṣun àwòrán, NAF

Bi o tilẹ jẹ pe awọn ikọ adaluru le, ti wọn si da ibọn bo o lati mu ni kete to balẹ amọ o raye sa mọ wọn lọwọ, to si ribi fara pamọ si titi ti oorun fi wọ.

"Laarin aajin yii ni ọgagun Dairo lo ina ara ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ lati fi riran, to si raye rin kọja laarin awọn agbegbe tawọn ikọ afẹjẹwẹ naa tẹdo si, titi to fi raye de ibudo ologun, nibi ti wsn ti gba silẹ.

O si yẹ ki gbogbo eeyan mọ pe ni kete ti wọn gbọ iroyin pe baalu ologun kan tun ti ja lulẹ, ni olori ileesẹ ologun ofurufu, Oladayo Amao, ti pasẹ pe ki wọn sa gbogbo aayan to yẹ lati doola awakọ ofurufu naa."

Àkọlé fídíò, Ilorin Cripple Couple: Ọṣẹ ìfabọ́ ni tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ ń tà láti bọ́ ọmọ mẹ́ta