Sallah Celebration: Márosẹ̀ Ibadan sí Eko dí pa torí ọdún Iléyá

Oju ọna marosẹ Eko si Ibadan to di pa

Tipa tipa lawọn eeyan fi n raye lẹyin tawọn oni kata kara agbo di opopona marosẹ ilu Eko sí Ibadan pa lọjọ Aiku.

Iroyin ti a gbọ ni pe awọn olowo ẹran ọja Kara patẹ ọja wọn soju titi, bi wọn ti n ta ọja fún ọdun Ileya.

Eyi lo si ṣe okunfa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ loju popo naa lẹyin ti ọna tawọn ọkọ n gba di ku tooro.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn akọroyin sọ pe sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ loju ọna awọn to n bọ wa si ilu Eko de agbegbe Alausa nigbati awọn to n jade lati ilu Eko de Olowotedo ni bii ago marun un irọlẹ ọjọ Aiku.

Niṣe lawọn to fẹ ra agbo gbe mọto wọn si ẹgbẹ mejeeji oju titi marọsẹ naa.

Awọn agbo fun tita tori ọdun Ileya

Awakọ ero kan, Ramon to n lọ si ilu Ibadan sọ pe iriri to buru jai loun ni loju popo naa.

"Inira lo jẹ fun wa ni bii ọsẹ melo sẹyin bayii.

Amọ, owo ọkọ to ti le sii ni ko jẹ ko dun mi pupọ ju.

Mo ni ireti pe ijọba wa yoo wa nkan ṣe si iṣoro yii nitori o n ṣakoba fun agọ ara wa," awakọ Ramon lo sọ bẹẹ.

Owo ọkọ Eko sí Ibadan ti o jẹ N1,500 sí N2,000 tẹlẹ ti di N3,000 sí N5,000 bayii.

N8,000 ni wọn n wọ ọkọ lati ilu Eko sí Warri bayii eleyii ti wọn n wọ ni N5,500 tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Ilorin Cripple Couple: Ọṣẹ ìfabọ́ ni tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ ń tà láti bọ́ ọmọ mẹ́ta

Ero ọkọ kan to n rinrin ajo bọ lati ilu Akure sí ilu Eko ni lẹyin ti oun lo wakati meji ninu sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ tan loun gun ọkada lọ si ibi ti oun n lọ.

Onibara ẹran agbo kan lọja Kara sọ pe oun gbe ọkọ oun soju ọna mọrọsẹ tori kò sí aye ti oun le gbe ọkọ oun si ninu ọja naa.

Ẹwẹ, oludamọran pataki si Gomina ipinlẹ Eko lori ọrọ ayika, Ola Oresanya sọ pe ijọba yoo ṣe ìpàdé pẹlu awọn oṣiṣẹ eleto abo lati dari awọn ọlọja ọhun.

Àkọlé fídíò, ''Ọjà ẹran àgbò kò yá bí ti ọdún tó lọ''